BUKUNMI OLÚWAṢINA, GBAJÚMỌ̀ ÒṢERÉ TÍÁTÀ SE ÌGBÉYÀWÓ BONKẸLẸ NÍTORÍ ÀÌSÍ OWÓ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 17, 2020

BUKUNMI OLÚWAṢINA, GBAJÚMỌ̀ ÒṢERÉ TÍÁTÀ SE ÌGBÉYÀWÓ BONKẸLẸ NÍTORÍ ÀÌSÍ OWÓ


Ọkàn lára àwọn irawọ òṣerébinrin nnì, Bukunmi Olúwaṣina lo tí ṣe ìgbéyàwó bonkẹlẹ pẹ̀lú olólùfẹ́ rẹ àtijọ́ báyìí, táwọn èèyàn sì ń kí ku oriire.

Bukunmi fúnra rẹ lo gbé fọto ìgbéyàwó náà sórí ìkànni ayélujára tí Instagiraamu rẹ laipẹ yìí, níbi táwọn olólùfẹ́ rẹ tí ń kí kú oriire náà. 

Lára àwọn àdúrà táwọn amòye èèyàn kan tún fi ń ranṣẹ sì í ní pe Ọlọ́run kò ní jẹ kò di iya-n-dagbe báwọn aṣiwaju rẹ nìdí ìṣe tíátà tó yàn láàyò ṣe ń ṣe lásìkò yìí.

Awuyewuye tó tẹ AWIKONKO lọ́wọ́ jẹ kò ye wá pé nítorí àìsí owó, àti pé àwọn olólùfẹ́ méjèèjì náà kò fẹ́ èrò rẹpẹtẹ ni kò jẹ kò pariwo ìgbéyàwó náà síta.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI