Ẹ MÚRA SILẸ FUN WÀHÁLÀ ŃLÁ, Ó ṢEÉ ṢE KÍ NÀÌJÍRÍÀ PÍN YẸ́LẸYẸ̀LẸ - WÒLÍÌ AYỌ̀DÉLÉ GB'ÀWỌN ÈÈYÀN LAMỌRAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 4, 2020

Ẹ MÚRA SILẸ FUN WÀHÁLÀ ŃLÁ, Ó ṢEÉ ṢE KÍ NÀÌJÍRÍÀ PÍN YẸ́LẸYẸ̀LẸ - WÒLÍÌ AYỌ̀DÉLÉ GB'ÀWỌN ÈÈYÀN LAMỌRAN


Gbajugbaja ojiṣẹ Ọlọ́run nnì, Primate Elijah Ayodele tí sọ pé pẹ̀lú bí nnkan ṣe ń lọ lásìkò yìí lorilẹ-ede Nàìjíríà, afaimọ ni kí Nàìjíríà má pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, to sì ni káwọn èèyàn máa múra silẹ gidigidi fún wàhálà ńlá.

Ko si nnkan méjì tó mú kí Primate Ayọdele sọ̀rọ̀ yìí jáde laipẹ yìí, bí kò ṣe bí owó epo rọbi àti iná mọnamọna tún ṣe lọ sókè sí í, èyí tó mú káwọn èèyàn máa sọ oríṣiríṣi nípa ìjọba Buhari. 

Primate Ayọdele to jẹ́ Aláṣẹ àti oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual Church káàkiri àgbáyé jẹ́ kó di mímọ pé lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run gba ẹnu òun sọ lọ́dún 2015 lo wá sí ìmúṣẹ pẹ̀lú bí owó epo rọbi àti owó iná mọnamọna ṣe lọ sókè, tó sì lo ó wà nínú àkọsílẹ̀ àkànṣe ìwé tòun gbé jáde lọdun náà, èyí tó pé ní Warnings tó The Nations. 

Ó wà kanminu lórí àwọn ìpinnu tí Ààrẹ ń gbé jáde lásìkò yìí, èyí tí kò mú ayé rọrùn fáwọn ọmọ Nàìjíríà àti olùgbé ibẹ̀. 

Síwájú sí í lo tún gbé àsọtẹ́lẹ̀ mi ín jáde wí pé ó ṣeé ṣe kí Nàìjíríà pín, àti pé káwọn èèyàn wa ni imurasilẹ fún rukerudo tó ń bọ̀ lọ́nà. 

Bákan náà lo tún ní owó dọla náà yóò tún lọ sókè ní í ẹẹdẹgbẹta náírà sì dọla kan. 

Ó ní Nàìjíríà nílò àdúrà tó pọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn aráàlú àti pé bẹ̀rẹ̀ láti ọdún tó ń bọ̀, ìyàn yóò bẹ̀rẹ̀ si i mú, tí kò sì ní sì oúnjẹ bí í tí tẹ́lẹ̀. 

Primate Ayọdele tún sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ síwájú sí í pé wàhálà ńlá yóò bẹ silẹ láàárín Ààrẹ Muhammadu Buhari ati Aṣiwaju ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Oloye Bọlá Ahmed Tinubu, tó sì jẹ pe àwọn àgbàlagbà àgbáyé ni yóò dà sí í. 

Ó ní Buhari yóò já Tinubu kulẹ, nítorí pé ìjọba Buhari kò ṣetan láti fi ipò silẹ pẹ̀lú pẹ̀lú pẹ̀lẹ́ kutu. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI