ỌPẸ O! ẸGBẸ̀RÚN MỌ́KÀNLÉLÓGÚN ÀBỌ̀ ARÁÀLÚ FẸẸ JẸ ÀǸFÀÀNÍ OWÓ ÌṢÒWÒ NÍ KWARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 3, 2020

ỌPẸ O! ẸGBẸ̀RÚN MỌ́KÀNLÉLÓGÚN ÀBỌ̀ ARÁÀLÚ FẸẸ JẸ ÀǸFÀÀNÍ OWÓ ÌṢÒWÒ NÍ KWARA


Gbogbo ìpínlẹ̀ Kwara lo mi tìtì jákèjádò lónìí Ọjọ́bọ tí í ṣe Tọside nígbà tí Gómìnà ìpínlẹ̀ náà, AbdulRahman AbdulRazaq kéde síta pé àwọn aráàlú tí kò dín ni ẹgbẹ̀rún méjìlélógún dín díẹ̀ {21,623} ni yóò jẹ àǹfààní Owó Iṣowo tijọba gbé kalẹ. 

Owó Iṣowo náà nijọba ṣe àgbékalẹ̀ rẹ fáwọn ọlọ́jà kéékèèké lábé eto ti wọn pé ní Kwara State Social Investment Programme (KWASSIP) láì ni èlé nínú rara. 
 
Ipele-ipele là gbọ pé ìjọba fẹẹ fi pín owó náà fáwọn èèyàn láti fi rán àwọn aráàlú lọ́wọ́, tá a sì gbọ pé ọsẹ márùn-ún gbáko ni wọn yóò fi pín owó náà fáwọn èèyàn. 

AWIKONKO gbọ pe igbesẹ yii waye lẹyin oṣu kan gbako ti wọn ti ṣe iwadii finifini lori awọn ti wọn yoo jẹ anfaani eto ẹyawo naa.

Alakoso eto naa, Mohammed Brimah jẹ ko di mimọ pe kaakiri gbogbo ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa n'ipinlẹ naa l'awọn eeyan yoo ti jẹ anfaani yii lai ṣe ojuṣaaju rara.
 
Ninu ọrọ rẹ, Brimah ni "Lonii ni eto Owo Iṣowo naa bẹrẹ, a n foju sọna lati pin owo f'awọn 21,623 ni ipele akọkọ yii. Latari Covid-19 to wa nita lasiko, a ni lati tẹle ilana to rọ mọ ọn, a maa jẹ k'awọn ti wọn ti yege fun anfaani yii mọ ibi ti wọn maa wa bi a ba ṣe n de ijọba ibilẹ wọn."

"Owo Iṣowo jẹ owo ti ko ni ele ninu rara, to si jẹ pe owo to kere julọ teeyan kan ṣoṣo le ri gba ni ẹgbẹrun mẹwaa naira. Lẹyin oṣu mẹfa ni wọn to o ni anfaani lati bẹrẹ si i da a pada lọna to ba ti rọ wọn lọrun."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI