ÌJÀMBÁ MỌTO F'Ẹ̀MÍ ÈÈYÀN MÉJÌ ṢÒFÒ DANU L'Ẹ̀PẸ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 1, 2020

ÌJÀMBÁ MỌTO F'Ẹ̀MÍ ÈÈYÀN MÉJÌ ṢÒFÒ DANU L'Ẹ̀PẸ́


Bí wọn ba n ra kòrò de ọrùn, àwọn méjì kan tí a kò mọ orúkọ wọn yóò ti dé ajule ọrùn níbi tí wọ́n ti wá lórí bí wọn ṣe pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàmbá mọto. 

Ọjọ́ Ajé, Mọnde là gbọ pé ìjàmbá náà wáyé lágbègbè Falawọ, ìkòríta Ẹ̀pẹ́ ń'ìjọba ìbílẹ̀ Ṣagamu. 

Àwọn ẹṣọ ààbò ojú popona ni wọn fi ìṣẹ̀lẹ̀ ijamba náà múlẹ̀ pé ọkọ Toyota Camry kan tó ní nọ́mbà idanimọ LSD 797 GJ lọ gbokiti lórí ère asapajude. 

Obìnrin kan àti ọmọdé-bìnrin kan ni wọn pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàmbá náà, táwọn méjì mi ín sí farapa. 


AWIKONKO gbọ pé ọsibítù Idẹra tó wà n'ilu Ṣagamu ni wọn kò àwọn tó farapa náà lọ fún ìtọ́jú, tí wón sì kó àwọn méjì tí wọn gba ekuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra lọ sí mọṣuari. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI