TRADER MONEY: ẸGBẸRUN LỌNA ỌGỌRUN ONIṢOWO GBE IGBA ỌPẸ NI KWARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, September 27, 2020

TRADER MONEY: ẸGBẸRUN LỌNA ỌGỌRUN ONIṢOWO GBE IGBA ỌPẸ NI KWARA


Awọn oniṣowo ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun (100,000) ni wọn ti gbe igba ọpẹ bayii, ti wọn si n dupẹ lọwọ Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq lori bi wọn ṣe fẹẹ jẹ anfaani owo idokowo ti ijọba ipinlẹ naa ṣagbatẹru ẹ labẹ eto ti wọn pe ni Social Investment Scheme.
 
Opin ọsẹ yii ni Gomina Abdulrazaq jẹ ko di mimọ pe awọn ẹgbẹrun lọna ọgọrun naa ni yoo jẹ anfaani ninu ipele akọkọ eto naa.
 
Rafiu Ajakaye to jẹ agbẹnusọ Gomina lori ọrọ iroyin lo f'idi rẹ mulẹ ninu atẹjade to fi ranṣẹ s'AWIKONKO laipẹ yii.
 
Ajakaye sọ pe lara awọn nnkan to jẹ ijọba logun ni igbayegbadun araalu, paapaa lati mu k'awọn eeyan maa ni awọn nnkan to n wọle fun wọn lojumọ, ati pe igbesẹ lati dẹkun iṣẹ ati oṣi ni.

O ni ṣaaju akoko yii l'awọn to le diẹ lẹgbẹrun mọkandinlogun (21,623) ti jẹ anfaani owo ẹgbẹrun mẹwaa naira ti wọn fi kun owo ọja wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI