JẸGẸDẸ LOUN TI GBA F'ỌLỌRUN LORI IDIBO TO WAYE L'ONDO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 12, 2020

JẸGẸDẸ LOUN TI GBA F'ỌLỌRUN LORI IDIBO TO WAYE L'ONDO


Igbimọ ipolongo idibo fun oludije sipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP n'ipinlẹ Ondo, Eyitayọ Jẹgẹdẹ ti sọ pe awọn ti gba kamu f'Ọlọrun lori idibo to waye l'opin ọsẹ to kọja naa.


Alakoso eto ipolongo fun Jẹgẹdẹ, Ọgbẹni Gbnega Akinmọyọ lo sọrọ yii lasiko to n fọrọ jomitoro ọrọ pẹlu lori ẹrọ amuhunmaworan ti ileeṣẹ Channels lọjọ Sande ana, to si ni bi Ọlọrun ṣe fẹ ni eto idibo naa ṣe waye.

“Eto ti Ọlọrun ti yan ni. Bo ṣe ri bayii, a maa duro. A maa duro de asiko Ọlọrun.

L'ọjọ Aiku-Sande ana ni ajọ eleto idibo lorilẹ-ede yii, ẹka t'ipinlẹ Ondo kede Gomina Rotimi Akeredolu s'ipo gomina lẹẹkeji, lẹyin to jawe olubori l'awọn ijọba ibilẹ mẹẹdogun ninu mejidinlogun to wa n'ipinlẹ naa.

Akinmọyọ wa a dupẹ lọwọ awọn ara ipinlẹ Ondo fun bi wọn ṣe dibo fun ẹni ti ọkan wọn n fẹ, bẹẹ lo dupẹ f'awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP fun aduroti wọn lasiko idibo naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI