NAIJIRIA TI N RIN NI BEBE ỌNA LATI TUKA - ARẸWA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, October 6, 2020

NAIJIRIA TI N RIN NI BEBE ỌNA LATI TUKA - ARẸWA

Aarẹ ẹgbẹ Arẹwa Consultative Forum, Yẹrima Shettima ti sọ pe orilẹ-ede Naijiria ti n rin ni bebe ọna lati tuka, iyẹn bi ko ba si igbesẹ lati tete ṣe atunto.

Yẹrima ni Atunto nikan ni itusilẹ ti orilẹ-ede Naijiria n fẹ lasiko yii, ati pe ọna abayọ kan ṣoṣo to wa nilẹ niyẹn.

Ki i ṣe pe Yẹrima deede sọrọ yii sita, bi ko ṣe ti atilẹyin to n ṣe si ọrọ alakoso agba fun ṣọọṣi Redeemed Christian Church of God, iyẹn Pasitọ Enoch Adejare Adeboye to sọ pe orilẹ-ede Naijiria nilo atunto ko to o pẹ ju.

Ṣaaju asiko yii Ni Baba Adeboye ti sọrọ jade sita pe ki Aarẹ Buhari gbe igbesẹ lati ṣe atunto orilẹ-ede yii ko maa ba a pin.

Yẹrima ninu ọrọ rẹ sọ pe bi Aarẹ Buhari ko ba tete gbe igbesẹ yii, afaimo ni ko ma jẹ pe ori ẹ ni Naijiria yoo ti tu, tonikaluku yoo si mọ ibi to duro si i.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI