NÍTORÍ KASNATY, ÌLÚ ABẸ́ÒKÚTA FẸẸ GB'ÀLEJÒ AWỌN ÈÈYÀN ŃLÁ L'ÀGBÁYÉ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 1, 2020

NÍTORÍ KASNATY, ÌLÚ ABẸ́ÒKÚTA FẸẸ GB'ÀLEJÒ AWỌN ÈÈYÀN ŃLÁ L'ÀGBÁYÉGbogbo eto lo tí parí pátápátá báyìí lórí ọ́fíìsì tuntun tí gbajugbaja sọ̀rọ̀ sọ̀rọ̀ àgbáyé nnì, Kọlawọle Atanda Adejojo, ìyẹn Kasnaty Sugar fẹẹ ṣí. 

Kò ṣeni tó dé ọ́fíìsì Kasnaty, ìyẹn SUGARLINK CONCEPTS to wá lágbègbè Agbelọba, Quary n'ilu Abẹ́òkúta tí kò ní í kú aje kú ikalẹ pẹ̀lú bí wọn ṣe fi owó dabira síbẹ̀. 


Ọjọ́ karùn-ún oṣù kẹwàá tí a wà yìí, ìyẹn ọjọ́ Ajé, Mọnde ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ yìí ni ìlú Abẹ́òkúta yóò gbalejo àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn káàkiri àgbáyé tí yóò wá bá Kasnaty Sugar ṣe ajọyọ ọ́fíìsì tuntun náà. 

Aago mẹ́wàá àárọ̀ ni eto yóò bẹ̀rẹ̀, tí a sì gbọ pé wẹjẹ-wẹmu yóò ṣẹlẹ̀ rẹpẹtẹ lọ́jọ́ náà. 

Ọ̀gá Kasnaty, Ọgbẹni Yẹmi Ṣonde ni yóò jẹ alaga àti olugbalejo ọjọ́ náà, gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ. 

Ọfiisi yìí ni Kasnaty yóò ti máa gbalejo àwọn onibara rẹ, tí yóò sì tún ti máa d'awọn èèyàn lóhùn, pàápàá àwọn tó bá fẹẹ gbé ìpolówó tabi ti wọn ba fẹ́ láti bá a dowo pọ. 

Ọjọ́ náà yóò larinrin kọjá afẹnusọ. 

Ṣá o, kí í ṣe gbogbo èèyàn ni wọn pé síbi ifilọlẹ ọ́fíìsì yìí lọ́jọ́ náà o nítorí alakalẹ ìjọba àti ileeṣẹ NCDC lórí ọ̀nà láti dẹkùn ajakalẹ àrùn Covid19 tó wà níta, èyí ló mú kí wọn fún gbogbo àwọn tó ń bọ̀ niwe. 

Ẹni tí kò bá ti ní káàdì àlejò lọ́wọ́ lọ́jọ́ náà kò ní láǹfààní láti wọlé, kí eku ilé gbọ, kò sọ fún t'oko. Ṣùgbọ́n síbẹ̀, àǹfààní wá fún gbogbo àwọn olólùfẹ́ Kasnaty láti wo bí eto naa ba se lọ sí lórí fesibuuku rẹ lọ́jọ́ náà: KASNATY SUGAR

Díẹ̀ rèé lára bí ọ́fíìsì náà ṣe riNo comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI