AWỌN DỌKITA TUN DA IṢẸ SILẸ L'ONDO, WỌN N BINU S'AKEREDOLU GIDI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 9, 2020

AWỌN DỌKITA TUN DA IṢẸ SILẸ L'ONDO, WỌN N BINU S'AKEREDOLU GIDI


Gbogbo awọn dọkita n'ipinlẹ Ondo bayii ni wọn n binu gidigidi si gomina wọn, Gomina Arakunrin Rotimi Akeredolu lori bo ṣe jẹ wọn lowo oṣu mẹrin pẹlu bi wọn ṣe n ṣiṣẹ to.
 
L'ọsẹ to kọja lọ lọhun l'awọn dọkita yii ti kọkọ da iṣẹ silẹ f'ọjọ meje lati fi kilọ fun ijọba lati san owo oṣu mẹrin to jẹ wọn, ṣugbọn ti wọn n'ijọba ko ri ti wọn ro.
 
Nigba ti wọn ri i pe ijọba ko gbe igbesẹ lati san owo oṣu naa, lo mu ki wọn sare ṣe ipade pajawiri lori ọna ti wọn tun fẹẹ gba lati le tete jẹ ki Gomina gbọ ti wọn.
 
Lẹyin ipade naa t'awọn dọkita yii labẹ asia ẹgbẹ wọn ti wọn pe ni 'Association of Resident Doctors of Nigeria' ni University of Medical Sciences Teaching Hospital, UNIMEDTH ṣe ni wọn fẹnuko wi pe afi k'awọn ṣi lọọ jokoo sile titi dígba t'ijọba yoo fi ri ti wọn ro.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI