ÀWỌN ÈÈYÀN MI N'ÍGBÀGBỌ́ NÍNÚ MI - OLUWO SỌ̀RỌ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, November 13, 2020

ÀWỌN ÈÈYÀN MI N'ÍGBÀGBỌ́ NÍNÚ MI - OLUWO SỌ̀RỌ̀


Oluwo tilu Iwo ni ipinlẹ Ọṣun, Ọba Abdulrasheed Akanbi, Telu kinni tí sọ pé láti ọdún márùn-ún sẹ́yìn tòun ti wá lórí ipò àwọn babanla òun, òun kò ti í ja àwọn aráàlú òun kulẹ rí. 

Fúnra Oluwo lo sọ̀rọ̀ náà laipẹ yìí ni Ààfin ẹ, tó sì ni inu awọn èèyàn máa ń dùn lọpọlọpọ ìgbà wí pé òun lòun wá lórí ipò náà fún ìdàgbàsókè. 

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ lo tún ti sọ síwájú pé "Mo kan lè bojú wo ẹyin, ìyẹn láti ọdún karùn-ún tí mo ti wá lórí ipò, mo sì lè fi ìgboyà àti ìdánilójú sọ pé 'mi ò ja àwọn èèyàn kulẹ. 

"Àwọn èèyàn mi ti mo jẹ ọba lé lórí sì ń tẹsiwaju. Inú wọn ń dùn pé wọn ní mi lórí ipò. Àwọn nkan ló ń sáré yí padà sí rere. 

"Ọlọ́run ti yí ìgbà àti asiko wọn padà sí rere, tó sì jẹ pe wọn ní ìrètí gidi fún òjò iwájú wọn. Èyí sì lóhùn tó máa ń fún mi ní ayọ̀. Igba mi dara igba mi san ilu ama debi giga Asewa !!!" 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI