BAAGI SIMẸNTI MEJI NI USMAN JI GBE L'ADO-EKITI, NI WỌN BA JUU S'ATIMỌLE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 17, 2020

BAAGI SIMẸNTI MEJI NI USMAN JI GBE L'ADO-EKITI, NI WỌN BA JUU S'ATIMỌLE


Adura 'ka ma ṣe r'ogun ikawọlori fẹsẹjọnlẹ'ko gba rara fun baale ile ẹni ọdun mejidinlogoji kan, Ifayin Usman ti wọn lo o ji baagi simẹnti meji nilu Ado-Ekiti lọjọ kejila oṣu yii, iyẹn Ọjọbọ-Tọsidee ọsẹ to kọja yii.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni nnkan bi aago meje kọja iṣẹju meje alẹ ọjọ naa ni Usman lọọ ji baagi simẹnti meji yii gbe lopopo NTA to wa nitosi oju ọna Ilawẹ nílu Ado-Ekiti, ti ọwọ si pada tẹ ẹ.
 
Ẹsun meji ọtọọtọ la gbọ pe wọn fi kan Usman n'iwaju ile ẹjọ Majisireeti to wa nilu Ado-Ekiti, eyi to ni i ṣe pẹlu ole jija, ti wọn si l'awọn ẹsun naa tako ofin ọdaran ipinlẹ naa t'ọdun 2012.
 
Ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Gilbert ni wọn lo o ni awọn simẹnti meji ti Usman ji gbe, ti wọn si ni iye owo rẹ jẹ ẹgbẹrun mẹfa naira.
 
Agbẹjọro to n tako Usman ni kọọtu bẹbẹ lati sun ẹjọ naa siwaju tori pe oun fẹẹ mu awọn ẹlẹri mẹta ọtọọtọ wa sile ẹjọ. Ṣaaju asiko yii ni Usman ti bẹbẹ pe oun ko mọ nkankan nipa ẹsun ti wọn fi kan oun.
 
Onidajọ ile ẹjọ naa,  Ọlanikẹ Adegoke ni aaye lati gba beeli Usman pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta naira ati oniduro meji ṣi silẹ, bẹẹ lo si sun igbẹjọ siwaju d'ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu yii

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI