Ẹ WO OJU AZEEZ ATI ADEỌLA TI WỌN FIPA B'ỌMỌ ỌDUN MẸRINLA L'AṢEPỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 9, 2020

Ẹ WO OJU AZEEZ ATI ADEỌLA TI WỌN FIPA B'ỌMỌ ỌDUN MẸRINLA L'AṢEPỌ


Ika abamọ l'awọn ọdọmọkunrin meji ti ẹ n wo yii mu sẹnu lasiko ta a kọ iroyin yii tan lori bi wọn ṣe fipa ba ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹrinla laṣepọ.
 
Ọmọ ogun ọdun ati ọmọ ọdun mejilelogun ni wọn pe Hammed Azeez ati Adeọla Ogunṣẹyẹ ti wọn fẹsun ifipabanilopọ kan lagbegbe Owo-Ẹgba.
 
Ọjọ kẹrin oṣ yii la gbọ pe ọwọ palaba awọn mejeeji segi lẹyin ti wọn lọ fi ọrọ wọn to awọn ọlọpaa leti.
 
AWIKONKO gbọ pe ni nnkan bi aago mẹjọ aabọ alẹ ọjọ kẹta oṣu yii, iyẹn ọjọ Iṣẹgun-Tusidee to kọja ni Azeez ati Adeọla ji ọmọ ọdun mẹrinla naa gbe, ti wọn si gbe e lọ sibi ti wọn ti fipa ja ibale rẹ.
 
Lẹyn ọpọlọpọ wakati ti wọn ti n wa ọmọ yii ta a fọrukọ bo laṣiri la gbọ pe wọn pada ṣalabapade rẹ lẹgbẹ igbo kan loju ọna ileewe, iyẹn School Road, Owode Ẹgba n'ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, ipinlẹ Ogun, to si ṣalaye nnkan to ṣelẹ f'awọn to ri i.
 
B'awọn ọlọpaa ṣe gbọ ọrọ yii ni ti bẹrẹ iwadii, tọwọ si pada tẹ wọn lọjọ keji.
 
Ọgba ọlọpaa ni wọn wa nibi ti wọn ti n sọ tẹnu wọn lasiko ta a kọ iroyin yii tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI