Ẹ̀KÚNWÓ BÚRẸ́DÌ: WỌN FẸ́ Ẹ́ BÁ MI L'ORUKỌ JE NI Ó - GÓMÌNÀ BELLO PARIWO SÍTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 15, 2020

Ẹ̀KÚNWÓ BÚRẸ́DÌ: WỌN FẸ́ Ẹ́ BÁ MI L'ORUKỌ JE NI Ó - GÓMÌNÀ BELLO PARIWO SÍTA


Gómìnà ipinlẹ Kogi, Yahya Bello tí sọ pé ibanilorukọ jẹ́ lásán ni ti atẹkade kan to n káàkiri orí ayélujára wí pé òun mọ nípa bí ìjọba ṣe fẹ́ máa gba owó orí lórí àwọn búrẹ́dì tó ń jáde káàkiri ipinlẹ náà. 

Laipẹ yìí ni ìròyìn náà gbà gbogbo igboro wi pe ijọba yoo maa gba owo ori lori eroja burẹdi ti wọ́n ba se jade nipinlẹ Kogi.

Atẹjade tileeṣẹ to wa fun eto okoowo ati ileesẹ aje nipinlẹ Kogi fi sita ni owo ori ọja lori burẹdi yoo mu ki owo to n wọle labẹle tubọ ru gọgọ si nipinlẹ naa.

Ẹwẹ, Gómìnà ìpìnlẹ̀ Kogi Yahaya Bello ti kéde pé, ìwà ìkà láti fí owó orí lé búrẹ́dì àti pé òun kò mọ̀ ǹkan kan nípa rẹ̀.

O ní ìwà àburu gbáà ni.

Ìgbákèjì gómínà, Edward Onoja nínú àjẹjáde kan tó fi síta ló sàlàyé pé owó orí ti àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ ìjọba fi sórí búrẹ́dì kò hàn sí gómìnà rará, ilé iṣẹ́ tó ń ri sí okóòwò àti ìdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ ló gbe jáde.

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀: "Gómìnà ní kí ń mu wá sí etí ìgbọ́ yín pé irọ́ gbáà ni owó orí tí wọ́n fi sórí ìṣù búrẹ́dì kọ̀ọ̀kan nípìnlẹ̀ Kogi".

"Kò sí òtítọ́ kan níbẹ̀ rárá, ó tún wá buru jáì pé wọ́n ní mó ti buwọ́lù ú, mí o búwọ́ lù ú, mí ò sì le búwọ́ lù ú rárá."

Owó orí òun bí Onoja ṣe sọ ọ yàtọ̀ sí ǹkan ti wọ́n ń polongo kiri lórúkọ ìjọba ipińlẹ̀ Kogi, kò sì ní bójú mu kí àwọn ènìyàn Kogi máa tẹ̀lé ìrú àwọn ọ̀rọ̀ báyìí, pàápàá jùlọ lẹ́yìn ìnira tí ààrùn Coronavirus ti kó bá ará ìlú.

Ó fi kun un pé àkọsílẹ̀ wà nínú ìwé ìròyìn pé, gómìnà ìpoińlẹ̀ Kogi Yahaya Bello ń já àwọn ogun àìfójú ri kan to jú èyí ti gómìnà kankan ti jà ní ìpińlẹ̀ Kogi lọ pàápàá jùlọ láti mú kí àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Kogi fi le wa ní àláfíà.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI