ẸMIR ILỌRIN Ń ṢAYẸYẸ ỌDÚN MÁRÙNDINLỌGBỌN LORI IPÒ, Ẹ GBỌ OHUN TÍ GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ SỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 11, 2020

ẸMIR ILỌRIN Ń ṢAYẸYẸ ỌDÚN MÁRÙNDINLỌGBỌN LORI IPÒ, Ẹ GBỌ OHUN TÍ GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ SỌ


Òní ni gbogbo agbaye ń bá Ẹmir tilu Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari yọ fún ti ayẹyẹ ọdún marundinlọgbọn lórí ipò àwọn babanla rẹ.

Báwọn èèyàn, pàápàá àwọn ọmọ ìlú Ilọrin ni ipinlẹ Kwara ṣe ń sọ oríṣiríṣi nípa ìdàgbàsókè àti ìṣọ̀kan tó ti dé bá ìlú náà látìgbà tí Ẹmir yìí tí jẹ́, bẹ́ẹ̀ làwọn kan ń gbé oṣuba káre fún un nípa ẹ̀mí ìṣọ̀kan yọ fi ń báwọn aráàlú ṣe nnkan papọ. 

Gómìnà ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq nínú atẹjade to fi ń kí Ẹmir náà, èyí tó gbé jáde laipẹ yìí ló ti sọ pé ìṣọ̀kan àti ìdàgbàsókè tó dúró ṣinṣin ni ìṣàkóso Ẹmir náà tí mú bá ìlú Ilọrin. 
 

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ, o ni ilu Ilọrin lábẹ́ ìṣàkóso Ọmọwe Sulu-Gambari kí í ṣe pé ó ń sáré dìde nípa ìdàgbàsókè àti gbajumọ láàárín àwọn ẹlẹgbẹ rẹ bí kò ṣe pé ó tún ní ifọkanbalẹ, àlàáfíà àti iṣọkan, èyí tó lo ń ṣagbatẹru eto ọrọ̀ ajé ìlú náà lọ́nà tó ye kooro. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI