IDAAMU DE B'AWỌN AKẸKỌỌ L'EKITI LORI ESI IDANWO WAEC, ṢUGBỌN IJỌBA TI SỌRỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 4, 2020

IDAAMU DE B'AWỌN AKẸKỌỌ L'EKITI LORI ESI IDANWO WAEC, ṢUGBỌN IJỌBA TI SỌRỌ


Idaamu nla lo de ba gbogbo awọn akẹkọọ ti wọn ṣẹṣẹ pari idanwo aṣekagba n'ile ẹkọ girama, iyẹn WAEC lonii Ọjọru-Wẹside lori bi wọn ko ṣe le ri esi idanwo ti wọn ṣe kọja.


Ọjọ Aje-Mọnde ijẹta ni ajọ to n ṣakoso eto idanwo aṣekagba l'awọn ile ẹkọ girama, iyẹn WAEC kede sita wi pe oun ti fi awọn esi idanwo naa sori ikanni ayelujara wọn, ati pe awọn akẹkọọ lanfaani lati lọ wo esi idanwo wọn.


Ni kete ti iroyin yii ti jade sita l'awọn akẹkọọ ti n lọ s'awọn ibudo ti wọn le ti yẹ esi idanwo naa wo kaakiri Naijiria, ṣugbọn to jẹ iyalẹnu wi pe gbogbo awọn akẹkọọ patapata n'ipinlẹ Ekiti ti wọn ṣe idanwo naa ni wọn ko ri esi ti wọn yẹwo.


Eyi lo mu k'ọkan awọn obi ma balẹ rara mọ, ti wọn si n beere pe ki lo le ṣẹlẹ.


Lara awọn nnkan to n ko ọkan wọn soke ni awuyewuye to n lọ kaakiri ipinlẹ naa wi pe ijọba ipinlẹ naa jẹ ajọ WAEC ni obitibiti owo, ti wọn si lo ṣeeṣe ko jẹ pe tori ẹ ni ajọ WAEC ko ṣe gbe esi idanwo naa sita.


Ṣugbọn ni bayii, ijọba ti sọ pe k'awọn eeyan lọ fọkan balẹ tori pe Ọjọ Ẹti-Fraide ọsẹ yii l'awọn ni i lero lati gba awọn esi idanwo naa jade.


Kọmiṣanna fọrọ iroyin, Ọgbẹni Akin Ọmọle sọ pe ijọba ko jẹ ajọ WAEC lowo kankan, ati pe idi ti wọn ko ti i ṣe gbe awọn esi idanwo naa sita ni awọn aṣiṣe to waye ninu esi idanwo naa, to si ni ki wọn maa f'oju sọna fun Ọjọbọ-Tọside ọla tabi ọjọ Ẹti-Fraide ọsẹ yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI