IWADII BẸRẸ LORI AWỌN TO PA OLUKỌ ILE ẸKỌ GBOGBONIṢE L’OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 24, 2020

IWADII BẸRẸ LORI AWỌN TO PA OLUKỌ ILE ẸKỌ GBOGBONIṢE L’OGUN


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe iwadii awọn ti bẹrẹ ni pẹrẹu lori awọn agbanipa ti wọn ṣeku pa ọkan lara awọn olukọni ile ẹkọ gbogboniṣe t’imọ ẹrọ, iyẹn D.S Adegbenro ICT Polytechnic, Itori to wa n’ijọba ibilẹ Ewekoro, ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Mufutau Waliu.
 
 
Ni nnkan bi aago meji ọsan ọjọ Iṣẹgun-Tusidee ọsẹ to kọja yii la gbọ pe awọn agbanipa dena de Waliu, ẹni ọdun marundinlogoji naa lọna lasiko to n kuro nile-ẹkọ naa, ti wọn si da ibọn bo o ninu mọto ẹ.

 

AWIKONKO gbọ pe mọto jiipu kan ti wọn pe ni Lexus, eyi ti wọn ni ko ni nọmba idanimọ la gbọ pe awọn agbanipa naa gbe lati fi ṣiṣẹ buruku naa, ti wọn si ni ṣe ni gilaasi rẹ dudu, eyi ti ko jẹ k’awọn eeyan kofiri awọn to wa ninu ẹ.

 

Bo tilẹ jẹ pe AWIKONKO ko gbọ nnkankan nipa awọn ti ọkunrin naa jọ ni adehun, eyi to le mu ki wọn ṣeku pa a lojiji, ṣugbọn ta a gbọ pe ibi ipade ti wọn ṣe ninu ọgba ile ẹkọ naa lo ti n bọ lọjọ naa ko to di pe wọn pa a.

 

Ṣe lọrọ naa dabi fiimu lori bi wọn ṣe pa ọkunrin yii nitori bi wọn ṣe l’awọn to n koja lo juba ehoro lasiko ti won fi moto naa dena re lati da emi e legbodo.

 

Agbenuso ile eko gbogbonise naa, Ogbeni Yinka Adegbite so pe o seni laanu wi pe okunrin naa jade laye, to si l’awon olopaa ti bere iwadii lori e.

 

Okunrin naa lo je ka mo pe awon olopaa ni won sare gbe e lo si osibitu ijoba to wa ni Ijaye nibi ti won ti fidi e mule pe o ti ku.

 

Ni bayii, ileese olopa ipinle Ogun ti so pe ona ti iwadii yoo gba waye koja eyi t’awon ti n se tele, to si ni gbogbo awon moto ti ko ba ti ni nomba idanimo lawon yoo bere si i gba lowo awon to n wa won kaakiri. 

 

Ileese olopaa ni awon to ba n lo gilaasi dudu (tinted glass) mo moto won lai gba ase lowo olopaa ni yoo bere si i foju ba ile ejo b’owo ba ti te won, to si fi d’awon eeyan loju pe laipe lowo yoo te awon to sise buruku naa.

 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI