WÀHÁLÀ MI-IN TUN DÉ BÁ SÀRÀKÍ, WỌN JẸRI TA KÒÓ NÍLÉ ẸJỌ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, November 13, 2020

WÀHÁLÀ MI-IN TUN DÉ BÁ SÀRÀKÍ, WỌN JẸRI TA KÒÓ NÍLÉ ẸJỌ́


Pẹ̀lú bí nnkan ṣe ń lọ yìí, afaimọ ni kí wọn má padà gba àwọn dúkìá Ààrẹ ilé igbimọ aṣofin àná lorilẹ-ede yìí, Ọmọwe Bukọla Sàràkí méjì tó wà n'ilu Èkó lórí báwọn èèyàn ṣe ń dìde láti jẹri tako ó wí pé owó ìjọba lo fi ko wọn jọ. 

Isiaka Kareem to jẹ́ alákòóso eto iṣuna tẹ́lẹ̀ {former Controller, Finance and Account} Nile ìjọba ipinlẹ Kwara lọ jẹri tako Bukọla Sàràkí nílé ẹjọ́ gíga àpapọ̀ tó wà n'ilu Èkó níwájú Onidajọ Mohammed Liman. 

Isiaka ní nígbà tòun wa n'ijọba, àpò owó ẹnìkan tó pé ní Abdul Adama làwọn máa ń ṣàn àwọn owó kan sì, tí wọn ká owó náà mọ àwọn owó eto ààbò. 

Ó ní gbogbo ìgbà tijọba bá ń ṣe eto iṣuna ipinlẹ náà ni wọn máa ń fi àwọn owó yìí há owó eto ààbò {security and contingency} láàárín. 

Ọkùnrin náà ni láàárín ọdún 2pp3 sì ọdún 2011 nígbà tí Sàràkí jẹ́ Gómìnà ipinlẹ Kwara lo fi gba àwọn owó yìí loṣooṣu, tó sì ni kò sí nnkan tòun fẹẹ ṣe láti má je ki owo naa jáde.

Ní báyìí, Onidajọ náà, Liman tí pàṣẹ pé kí igbẹjọ tesiwaju lọ́jọ́ karundinlọgbọn oṣù yìí. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI