2021: ETO ẸKỌ, OWO OṢU TUNTUN ATI IRO LAGBARA AWỌN ỌDỌ GBARADA NINU ETO IṢUNA IPINLẸ KWARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 16, 2020

2021: ETO ẸKỌ, OWO OṢU TUNTUN ATI IRO LAGBARA AWỌN ỌDỌ GBARADA NINU ETO IṢUNA IPINLẸ KWARA


Titi di asiko ta a kọ iroyin yii tan l'awọn oṣiṣẹ ijọba at'awọn ọdọ n'ipinlẹ Kwara ṣi n fo fun ayọ lori bi wọn ṣe sọ pe oriire nla lo wọle tọ wọn l'ọdun 2021 to n bọ lọna yii, pẹlu bi ijọba ṣe fẹẹ da obitibiti owo si ẹka eto ẹkọ, irolagbara awọn ọdọ ati owo oṣu tuntun t'awọn oṣiṣẹ yoo maa gba.
 
Ọjọ Iṣẹgun ti i ṣe Tusidee ana ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq gbe aba eto iṣuna ọdun 2021 lọ siwaju awọn igbimọ aṣofin ipinlẹ naa lati bu ọwọ lu. Eto iṣu naa la gbọ pe biliọnu mọkanlelogun le diẹ, iyẹn N123,091,307,468 naira ni wọn fẹẹ lo f'ọdun 2021.
 
Ninu aba eto iṣu naa ni Gomina ti sọ pe oun ti kan s'awọn ọjọ kaakiri eto iṣẹ ijọba lati ṣe iwadii ni kikun ati lẹkunrẹrẹ nipa bi wọn yoo ṣe na owo, ti apapọ rẹ si jẹ miliọnu mọkanlelogun le diẹ naira.
 
Gomina AbdulRazaq sọ peawọn ti ṣetan lati san owo oṣu tuntun f'awọn oṣiṣẹ, bẹrẹ lati oṣu kinni ọdun 2021, ti awọn ọdọ naa yoo si jẹ anfaani mudunmudun eto ijọba awaarawa, paapaa t'awọn akẹkọọ naa yoo jẹ igbadun eto ẹkọ igbalode.
 
O ṣalaye pe:
Eto Ẹkọ - 25.5%
Eto Ilera - 13.7%
Akanṣe Iṣẹ - 25.7% at'awọn  mi in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI