ABDULRAZAQ GBÉ OṢUBA FÚN BUHARI L'ORI ÀWỌN ỌMỌ TI WỌN GBA PADÀ LỌ́WỌ́ ÀWỌN AJINIGBE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, December 18, 2020

ABDULRAZAQ GBÉ OṢUBA FÚN BUHARI L'ORI ÀWỌN ỌMỌ TI WỌN GBA PADÀ LỌ́WỌ́ ÀWỌN AJINIGBE


Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq tí gbé oṣuba káre fún Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Mohammadu Buhari lórí iṣẹ takuntakun tó ṣe láti rí í pé wọn gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọn jì gbé padà. 
 
Bẹ́ẹ̀ lo tún ń bá gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe ajọyọ bi wọn ṣe rí àwọn ọmọ náà gbà padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ajinigbe. 

Laipẹ yìí làwọn agbebọn yawọ iléèwé kan nipinlẹ Kaduna, níbi tí wọn tí jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí kò dín ni ọọdunrun gbé lọ, táwọn òṣìṣẹ́ ológun sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ lójú ẹsẹ. 

Gomina AbdulRazaq ni bí wọn ṣe rí àwọn ọmọ náà gbà padà kò ṣẹyin akitiyan Ààrẹ Buhari ati Gomina ìpínlẹ̀ Kaduna, Aminu Masari. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI