Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara lábẹ́ ìṣàkóso Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq tí sọ pé asiko ti tó láti gba gbogbo dúkìá ìjọba tí lu tá ni gbanjo padà lọ́wọ́ àwọn tí wọn tá a fún.
Lónìí tí í ṣe Ọjọ́ru, ìyẹn Wẹside ni igbimọ tí Gomina gbé kalẹ láti ṣe ìwádìí àwọn dúkìá ìjọba tí wọn tá lọ́nà eru jabọ gbogbo àwọn ìwádìí wọn.
AWIKONKO gbọ́ pé pupọ nínú àwọn dúkìá ìjọba ni wọn tá danu lọ́nà tí kò bá òfin mú, táwọn tó ra wọn sì ti yọjú láti ṣàlàyé fún igbimọ náà.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Adajọ-fẹyinti Ọlabanji Orilonishe sọ pé ṣe làwọn ìjọba tó kọjá lọ lo ipò wọn lọ́nà tí kò tọ́ láti fi tà gbogbo dúkìá náà dànù ni gbanjo.
O ni nínú àwọn ìpínlẹ̀ méjìlá tí wọn dá silẹ lọ́dún 1967,eyi ti ìpínlẹ̀ Kwara náà wá lára wọn, ìwà yìí ló ń ṣàkóbá fún ìdàgbàsókè, ìyẹn níbi tí wọn tí ń tà dúkìá ni gbanjo.
Bẹ́ẹ̀ lo fi kún ọ̀rọ̀ rẹ wí pé àwọn tí ṣe akojọpọ gbogbo àbájáde ìwádìí àwọn sínú àwọn ìwé ńlá mẹ́ta kan tó gbé fun Gómìnà, èyí tó kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí.
Bẹ ó bá gbàgbé, ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹjọ ọdún yìí NI Gómìnà AbdulRazaq gbé igbimọ náà kalẹ láti tọpinpin báwọn ìjọba tó kọjá lọ ṣe tá àwọn dúkìá ìjọba láti ọjọ́ kọkandinlọ̀gbọn oṣù karùn-ún ọdún 1999 sì ọjọ́ kọkandinlọ̀gbọn oṣù karùn-ún ọdún 2019.
No comments:
Post a Comment