BÀBÁ ARÚGBÓ KU SÓRÍ AṢẸ́WÓ L'OTẸẸLI, WỌ́N NÍBI TO GBÀ WÁ SÁYÉ NÁÀ LO TÚN GBÀ LỌ S'Ọ̀RUN, KÍ Í ṢE ẸJỌ Ẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 21, 2020

BÀBÁ ARÚGBÓ KU SÓRÍ AṢẸ́WÓ L'OTẸẸLI, WỌ́N NÍBI TO GBÀ WÁ SÁYÉ NÁÀ LO TÚN GBÀ LỌ S'Ọ̀RUN, KÍ Í ṢE ẸJỌ Ẹ


Kàyéfì ńlá lọrọ bàbà arúgbó ẹni ọdún mẹrindinlaadọrin {66} kan, William Agyei ṣí ń jẹ fún pupọ àwọn èèyàn tó gbọ́ lórí bo ṣé kú sórí aṣẹ́wó ni ile ìtura. 

Aṣẹ́wó náà tí wọn lọmọ ọdún marundinlọgbọn là gbọ́ pé William gbé lọ sí otẹẹli kan tó wà lágbègbè Koforidua orílẹ̀-èdè Ghana.

Ohun tá a gbọ ni pé mọto pupa Toyota Corolla tí nọ́mbà idanimọ ẹ jẹ ER 1614-17 lo fi gbé ọmọbìnrin náà lọ sí ilé ìtura yìí lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá, ìyẹn ọjọ́ Satide-Abamẹta. 

Bí wọn ṣe wọnú yàrá là gbọ́ pé wọn gbádùn ara wọn. Ibi tí wọn tí ń kó ibasun fún ara wọn lọ́wọ́ là gbọ pé Baba náà tí ṣubú lulẹ, tó sì bẹ̀rẹ̀ si í japoro. 

Ojú ẹsẹ̀ ni wọn sọ pé ọmọbìnrin náà tí sáré gbé baagi ẹ, tó sì júbà ehoro lai jẹ́ kẹnikẹni mọ nípa ẹ. 

Àárọ̀ ọjọ́ kejì là gbọ́ pé àwọn òṣìṣẹ́ otẹẹli náà wọ yàrá láti tún inú yàrá náà ṣe, tí wọn sì ni ṣe ló bá bàbà náà lórí bẹẹdi, tí kò lè dìde. 

Èyí ló jẹ́ kó pariwo síta, ìyẹn lánàá sáwọn tó wà layika, tí wọn sì sáré debẹ láti wo nnkan tó ṣẹlẹ̀. 

Lójú ẹsẹ̀ ni wọn ti pé àwọn ọlọpaa Effiduase láti wá a wo nnkan tó ṣẹlẹ̀. Nibẹ ni wọn ti bá oríṣiríṣi nnkan ti wọn fi ń ní agbára fún ibalopọ bí í viagra for men, deep heat spray, unirob polar ice, bendroflumethiazide tablets, àtàwọn nnkan mi ín. 

Àwọn ọlọpaa ni wọn padà gbé òkú náà lọ sí mọṣuari St Joseph to wá nítòsí fún àyẹ̀wò tí wọn ń ṣe sí ara òkú, ìyẹn autopsy. 

Ohun táwọn èèyàn ń sọ ní pe ibi tí bàbá náà gbà sì ayé lo padà gbà lọ sọrun alakeji. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI