DINO MELAYE TI N BẸ JONATHAN PADA, O LOUN TI RONUPIWADA BAYII - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 16, 2020

DINO MELAYE TI N BẸ JONATHAN PADA, O LOUN TI RONUPIWADA BAYII

Ọkan lara awọn gbajumọ Sẹnetọ lorilẹ-ede Naijira, Sẹnetọ Dino Melaye to ṣoju ẹkun Kogi ti n rawọ ẹbẹ si Aarẹ ana lorilẹ-ede yii, Goodluck Ebele Jonathan wi pe ko dariji oun, tori pe oju oun ti la s'awọn aṣiṣe nla toun hu si Aarẹ ana.
 
Melaye sọ pe awọn iwa t'oun hu si goodluck Jonathan ko ṣeyin bi oju oun ṣe dudu, toun ko si mọ nnkan toun n ṣe, ati pe ni bayii, iye oun ti sọ pada, oun si ti i ri i pe aṣiṣe nla gba a loun hu. 
 
Lasiko ti wọn n se ifilọlẹ iwe kan ti wọn fi peri Jonathan ni Melaye fi ọrọ yi lede nilu Abuja. 
 
Lara awọn to doju ija kọ ijọba Jonathan ni idibo ọdun 2015 ni Melaye wa to si polongo takuntakun lati tako Aarẹ ana naa ati awọn igbesẹ ti ijọba rẹ gbe paapa julọ nipa aabo ati eto ọrọ aje. 
 
Dino ṣalaye pe lọpọ igba ni igbe aye oun ko dan mọran laarin ọdun marun to kọja yii debi pe oun fẹẹ le gbẹmi ara oun. 
 
''Emi Sẹnẹtọ Dino Melaye mo sọ nitagbangba pe lẹyin ọpọ isẹlẹ ati awọn ohun toju wa ti ri bayi, mo fẹ sọ pe nigba kan loju mi di, ṣugbọn bayi o ti la kedere."
 
Bẹẹ naa ni Melaye gbosuba kare fun Aarẹ Jonathan fun igbesẹ pipe aarẹ Buhari lori ago lati gba pe oun padanu ibo ọdun 2015. 
 
O ni labẹ eleyi ati iwoye iru nkan to n sẹlẹ ni Amẹrika ti aarẹ Donald Trump ko fẹ gba pe oun ti fidirẹmi ninu idibo, o yẹ ka kan saara si Jonathan. 
 
Yatọ si Dino Melaye, awọn eekan miran to wa nibi ifilọlẹ iwe yi ti wọn pe akọle rẹ ni "Dear President Goodluck Jonathan (An Open Letter)," ti akọroyin kan Bonaventure Philips Melah kọ, tunbọ gbosuba kare fun Jonathan. 
 
Lara wọn ni Gomina ipinlẹ Kano to wa ninu ẹgbẹ oselu APC to ni awọn mọ riri eto Almajiri ti aarẹ Jonathan gbe kalẹ lati koju ipenija awọn ọmọ Almajiri ti ko ri ẹkọ to peye gba. 
 
Aarẹ Jonathan ni aarẹ Nigeria akọkọ to pe alatako lati ki i ku orire aseyọri ninu idibo botilẹ jẹ wipe awọn kan sọ pe ijọba rẹ faye gba awọn aisedeede kan bi iwa ajẹbanu ati aidoju ija kọ awọn ikọ Boko Haram bo ti se yẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI