HAAAAA! MIDE MARTINS F'ORÍ GBÁ'LẸ̀ LÓRÍ ÌTÀGÉ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, December 20, 2020

HAAAAA! MIDE MARTINS F'ORÍ GBÁ'LẸ̀ LÓRÍ ÌTÀGÉ


Kí fíìmù kan tó o di àgbéléwò, nnkan kékeré kọ ní ojú àwọn òṣeré tíátà máa ń rí lóko ère, torí Yorùbá bọ̀ wọn sọ pé títa ríro là ń kọ ilà, tó bá jinná tán ló ń di oge. Bẹ́ẹ̀ gẹlẹ lọrọ àwọn òṣeré tíátà náà rí bí wọn ba n pò iṣẹ papọ̀ lọ́wọ́. 

Ọkàn lára àwọn gbajugbaja osere tiata Yorùbá nnì, Mide Martins ti n ke irora bo ti ṣe fori janlẹ lasiko to n ṣe ere sinima kan lọwọ.

A gbọ ibi tó ti ń bá ọkọ rẹ nínú fíìmù náà lo agídí lọ́wọ́ lo3ti déédéé ṣubú lulẹ, tó sì forí gbalẹ, ṣùgbọ́n tí wọn ní kàkà kó pariwo, ṣe ló tún ń bá iṣẹ tí orí rán án lọ. 

Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fáwọn tí wọn jọ wá nibẹ, tí wọn sì ń sọ pé obìnrin náà mọ nnkan tó ń ṣe, ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí wọn yà siini náà tán lo ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún wọn pé orí náà ń fọ òun. 

Ikede yi to fi soju opo rẹ ni Instagram lo sọ pe ara oun ko ti ya daada nitori bi oun ti ṣe fori gbalẹ.

Ninu ọrọ to fi tẹle fọnran fidio ati aworan boti ṣe farapa yi han, Mide sọ pe ''Igbesi aye awa oṣere tiata ko dẹrun!''


O ni ''Ara mi ko ti bọ sipo latari bi mo ṣe forigbalẹ. Ki eledua fi oore si igbiyanju gbogbo ni to n wa atijẹ ati mu''

Okiki Bakare@kikibakare ti wọn jijọ n ṣe ere naa ti ko ti jade kan sara si Mide Martins bi o ti ṣe fi inira ori to la mọlẹ mọra .

O ni eyi ṣafihan pe ojulowo osere tiata ni Mide n ṣe ti o si ni ki eledua tete mu lara da.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI