MO TI YỌ ỌWỌ KÚRÒ NÍNÚ ÒṢÈLÚ - ỌṢHIỌMHỌLẸ PARIWO SÍTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, December 8, 2020

MO TI YỌ ỌWỌ KÚRÒ NÍNÚ ÒṢÈLÚ - ỌṢHIỌMHỌLẸ PARIWO SÍTA


Alága ana fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Adams Ọṣhiọmhọlẹ ti sọ pe oun ti yọwọ kuro ninu ọrọ oṣelu orilẹ-ede yii, toun si tun ti dariji gbogbo awọn to ṣagbatẹru bi wọn ṣe yọ oun kuro nipo alaga.
 
Ọṣhiọmhọlẹ lo sọrọ naa nin u atẹjade kan to fi sita ni ọjọ Aje ti i ṣe Mọnde ana, nibi to ti sọ pe oun ti sọ f'awọn agbẹjọro oun lati jawọ kuro ninu gbogbo ẹjọ to wa nile ẹjọ.
 
Ninu atẹjade naa lo tun ti sọ pe oun ko ni i gba lati du ipo alaga naa mọ, ati pe bi ile ẹjọ ba da oun lare, oun ko ṣetan lati pada sipo naa mọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI