O MA ṢE O! AISAN KIDINRIN TUN GBE GBAJUMỌ OṢERE TIATA ṢANLẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, December 6, 2020

O MA ṢE O! AISAN KIDINRIN TUN GBE GBAJUMỌ OṢERE TIATA ṢANLẸ


Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, inu irora aisan kidinrin ni gbajugba oṣere tiata nni, Adewale Adeyẹmọ wa, to si nilo iranlọwọ awọn ẹlẹyinju aanu.
 
AWIKONKO gbọ pe ọdun diẹ sẹyin ni aisan yii ti n ba agba oṣere tiata aderinpoṣonu naa finra, to si ti na ọpọlọpọ owo lee lori, ko le gbadun.
 
 
Ṣugbon asiko yii, nnkan ko rọrun rara fun ọkunrin nigba ti wọn ni ṣe ni aisan naa gba ọna mi in yọ, to si ti wa l'ọsibitu lati bi ọjọ meloo kan sẹyin.
 
Iranlọwọ owo nla ti wọn yoo fi ṣiṣẹ abẹ ni ọkunrin naa n beere fun ko to pẹ ju, ko si le pada s'idi iṣẹ tiata to yan laayo.
 
Fun ẹnikẹni to ba fẹẹ ran Adeyẹmọ lọwọ, akanti ile ifowopamọ si rẹ to jẹ ti Access Bank lẹ le ba a fi owo ranṣẹ si, ko si iye to kere ju lati fi ran ọkunrin naa lọwọ. Ẹ ṣeun.

Orukọ Akanti: Adeyemo Adewale
Nọmba Akanti: 0031722753
Banki: Access Bank.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI