OLISA METUH: FAYOṢE GBADURA BURUKU FUN ADAJỌ ABANG - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, December 25, 2020

OLISA METUH: FAYOṢE GBADURA BURUKU FUN ADAJỌ ABANG


Ko jọ bi epe, ko jọ bi adura ni Gomina ana n'ipinlẹ Ekiti, Peter Ayọdele Fayoṣe fi ranṣẹ si Onidajọ Okon Abang lalẹ ana ni ko pẹ ti wọn tu agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party tẹlẹ, Olisa Metuh silẹ.
 
Anan ti i ṣe Tọside ni Olisa Metuh gba ominira kuro ni ọgba ẹwọn Kuje to wa nilu Abuja lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
 
Fayoṣe ni awọn asiko to le koko ki i pẹ, ṣugbọn awọn alagbara lo maa n pẹ. 
 
Ninu ọrọ to kọ sori ikanni ayelujara ti Twitter lo ti sọ pe "Ni ti Onidajọ Abang, gbogbo ere iṣẹ ọwọ ẹ lati ko inira ati iya ba eto idajọ to n jẹ k'awọn ọmọ Naijiria maa koju lo maa jẹ"
 
Lọjọ kẹrindinlogun oṣu yii ni ile ẹjọ kotẹmilọrun to wa nilu Abuja da ẹjọ ti wọn fi ju Metuh sẹwọn ọdun meje nu, eyi ti Onidajọ Okon Abang da nile ẹjọ giga tilu Abuja.
 
Irọlẹ ọjọ Ẹti ti i ṣe Fraide ọsẹ to kọja ni Metuh ja ajabọ lọgba ẹwọn Kuje.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI