OPIN ỌDUN: WỌN DA ẸJỌ IKU FUN MUSTAPHA TO LU OLOLUFẸ Ẹ PA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 31, 2020

OPIN ỌDUN: WỌN DA ẸJỌ IKU FUN MUSTAPHA TO LU OLOLUFẸ Ẹ PA


Ana ti i ṣe Tusidee ni ile ẹjọ giga to wa ni Ringim, ipinlẹ Jigawa da ẹjọ iku fun gendekunrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn kan, Mustapha Idrith lori ẹsun wi pe o pa ololufẹ rẹ.
 
Ọjọ kejidinlogun oṣu kinni ọdun yii, lọwọ tẹ Mustapha lori ẹsun yii nigba ti wọn sọ pe ṣe ni gendekunrin naa yọ ọbẹ ọsan to n ta, to si fi dunbu ololufẹ rẹ naa, iyẹn Nafisa Hashim l'abule Daneji.

Ilu Abuja ni wọn sọ pe Mustapha ti n ta ọsan f'awọn eeyan mu.
 
Ẹsun ti wọn ni Mustapha fi kan Nafisa ni pe o loyun f'oun lai ti i jẹ káwọn ṣe igbeyawo, to si loun ko le pa itiju naa mọra, ayafi boun ba pa a danu lati ṣe e ni oku-oru.
 
Onidajọ Ahmed Muhammad Abubakar to da ẹjọ naa sọ pe ẹsun ti wọn fi kan Mustapha tako ofin orilẹ-ede yii, to si ni idajọ iku ninu. O wa paṣẹ pe ki wọn lọ yẹgi fun Mustapha digba ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI