Atimọle ọlọpaa làwọn ọ̀rẹ́ meji tí ẹ ń wo yìí yóò ti ṣe ayẹyẹ ọdún Kérésìmesì ọdún 2020 yìí lórí bí wọn ṣe fipá bá ọmọbìnrin kan tí wọn jọ ń gbé inú ilé kan náà lo pọ, tí wọn sì tún yà fọ́nrán rẹ.
Ki í ṣe bí wọn ṣe yà fọ́nrán náà lo ṣàkóbá fún wọn, bí kò ṣe bí wọn ṣe ń dunkooko mọ ọmọbìnrin náà wí pé kò gbọ́dọ̀ tú àṣírí síta, àti pé tó bá gbìyànjú ẹ, àwọn yóò fi fọ́nrán náà sórí ayélujára láti fi ṣe ẹlẹya.
Ọjọ́ kejìlá oṣù tí a wà yìí làwọn méjèèjì, Emmanuel Okori, ọmọ ogún ọdún àti Damilare Oyeniyi tòun jẹ́ ọmọ ọgbọ́n ọdún fipá bá ọmọbìnrin ọmọ ọdún mọkandinlogun náà laṣepọ lágbègbè Sango, ìpínlẹ̀ Ogun.
Ọjọ́ kẹrindinlogun oṣù yìí lọ́wọ́ palaba wọn segi, nígbà tí wọn ní ọmọbìnrin náà gbà teṣan ọlọpaa lọ láti lọ fi ẹjọ́ sùn.
Àwọn méjèèjì tí jẹwọ pé lóòótọ́ ni, ati pe iṣẹ́ ni, torí àwọn ko mọ pe ìwà náà yóò padà rán àwọn lẹwọn.
Ọga ọlọpaa ìpínlẹ̀ Ogun, Edward Ajogun tí pàṣẹ pé kí wọn lọ fi wọn pamọ sahamọ dìgbà tí ìwádìí yóò fi parí pátápátá, kò tó di pé wọn fi ojú bá ilé ẹjọ́.
No comments:
Post a Comment