ORIIRE ỌDUN TUNTUN: IJỌBA KWARA FẸẸ GBA OLUKỌ ẸGBẸRUN MARUN SIṢẸ N'IBẸRẸ ỌDUN TUNTUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, December 31, 2020

ORIIRE ỌDUN TUNTUN: IJỌBA KWARA FẸẸ GBA OLUKỌ ẸGBẸRUN MARUN SIṢẸ N'IBẸRẸ ỌDUN TUNTUN


Orin tuntun ni gbogbo awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara n kọ lasiko yii, to si jẹ pe ko sẹni to de ipinlẹ naa lasiko yii ti ko ni i mọ pe inu idunnu nla ni wọn wa, paapaa awọn ọdọ ti ko ti i n'iṣẹ gidi lọwọ.
 
Lonii ni ijọba ipinlẹ naa kede sita pe awọn ti ṣetan lati gba awọn olukọni ẹgbẹrun marun in diẹ, iyẹn 4,701 siṣẹ, ti eto fiorukọ silẹ yoo si bẹrẹ lati ọjọ kẹta ọsu kinni ọdun 2021.
 
Ori ikanni ayelujara la gbọ pe gbogbo awọn to ba fẹẹ ṣiṣẹ olukọni yoo ti lọ maa gba fọọmu wọn lọfẹẹ bẹrẹ lati ọjọ kẹta ti i ṣe ọjọ Aiku, Sande to n bọ yii.

A gbọ pe 2,701 l'awọn olukọ ti wọn fẹẹ gba pẹlu imọ ẹkọ NCE s'awọn ile ẹkọ alakọbẹrẹ, iyẹn Basic Schools, ti wọn si ni wọn gbọdọ yanranti ninu ẹkọ iṣiro ati ede oyinbo pẹlu iṣẹ mẹta mi in.

Bakan naa láwọn ẹgbẹrun meji ti wọn fẹẹ gba si eto ẹkọ ti Teaching Service Commission (TESCOM). Awọn to ba fẹẹ gba fọọmu nipele yii gbọdọ ni imọ ẹkọ Bachelor's Degree l'awọn ẹkọ ti wọn ba fẹẹ yan laayo.
 
Alẹ ọjọ Aiku Sande to n bọ yii ni wọn yoo ṣi ikanni ayelujara ETO IGBANI SIṢẸ KWARA  f'awọn to ba fẹẹ forukọ silẹ, ti wọn yoo si ti i pa lọjọ kẹrindinlogun oṣu kinni ọdun 2021.
 
Eto idanwo la gbọ pe yoo waye lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ karundinlọgbọn oṣu kinni, bẹrẹ lati aago mẹwaa owurọ, ti ifọrọwanilẹnuwo yoo si waye lọjọ kini oṣu keji si ọjọ kẹfa oṣu keji naa.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI