Ẹsẹ ko gbero ninu gbọ̀ngàn àlejò ti Conference Hall of Abeokuta Chamber of Commerce to wa ni Oke-Igbein nilu Abẹ́òkúta nibi ti ileeṣẹ Tropic Reporters Media Communications ti fi aami ẹyẹ, ìyẹn Awọọdu da awọn eeyan lọla.
Ọdọmọde akọroyin, Ọgbẹni Adejọla Adéyẹmí Crown ni aláṣẹ ati Olùdásílẹ̀ ileeṣẹ Tropic Reporters to ṣagbatèru Tropic Reporters Choice Award ati 4th Anniversary Lecture to waye nilu Abẹ́òkúta lónìí ọjọ Aiku ti i ṣe Sande.
Eeyan ti ko din ni mejila láwọn ti ileeṣẹ naa fi aami ẹyẹ da lọla lati fi mọ riri awọn ipa rere tí wọn n ko lawujọ.
Nigba to n ṣe idanilẹkọọ, Ọgbẹni Irebami Ṣoyinka to jẹ ọkan lára àwọn olukọ ni ẹka ikẹkọọ eto iroyin ati iṣẹ igbohunsafẹfẹ (Mass Communication) ilé ẹkọ fasiti McPherson n'ipinlẹ Ogun, o ni pataki ni iṣẹ iroyin jẹ ninu idagbasoke agbegbe, paapaa orilẹ-ede.
Níbẹ lo ti yannanaa awọn adojukọ to n koju iṣẹ iroyin awọn agbegbe káàkiri àgbáyé, paapaa lorilẹ-ede Naijiria.
Alaga eto naa, Alaaji Wasiu Babatunde Ọlalẹyẹ to jẹ Ààrẹ Ogun State Chamber of Connerce and Industry nigba to n ṣàpèjúwe oludasilẹ ileeṣẹ Tropic Reporters Media Communications, Ọgbẹni Adejọla Adeyẹmi Crown ni eeyan toun ti mọ tipẹ ni, to si ni ifarabalẹ púpọ.
O ni ko wọpọ awọn ọdọ lasiko yii lati ni itara fun iṣẹ ti wọn yan laayo, to si ni iru awọn igbesẹ ti Adejọla n gbe ti fi han pe o ni ọjọ iwaju rere.
Lara awọn to wa níbẹ ni Ọba Ṣanusi Abdulwaheed Alani, Olu tilu Alabata; Ọmọba Dimeji-Kayọde Adedeji to jẹ aláṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Pen Pushing; Ọmọba Abiọdun Laṣilẹ; Ọgbẹni Adeyinka Adegbitẹ, Ọmọ Baba Tiṣa at'awọn mi in.
Diẹ ree lara awọn to gba awọọdu naa:
No comments:
Post a Comment