Angẹli 'Iku' n kan ilẹkùn Ààrẹ Nàìjíríà ati Ààrẹ Ivory Coast - Àpọsítélì Okikijesu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, April 18, 2021

Angẹli 'Iku' n kan ilẹkùn Ààrẹ Nàìjíríà ati Ààrẹ Ivory Coast - Àpọsítélì Okikijesu


Gbajugbaja òjíṣẹ Ọlọrun nni, Àpọsítélì Paul Okikijesu ti sọ pe afi ki awọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ti Ivory Coast maa gbadura kikankikan fun awọn Ààrẹ wọn lati ma jẹ ki wọn ku lojiji.

Bakan naa lo tun sọ pe ọkan lára àwọn akíkanjú ni Naijiria maa jade laye loṣu kẹrin ti a wa yii.

Àpọsítélì Okikijesu lo sọrọ naa lopin ọsẹ to kọjá yii ninu atẹjade to gbe sita wi pé a fi k'awọn olori ẹsìn dide ádùrá fun awọn olori naa.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Ẹ gb'adura lodi si ikú àwọn Ààrẹ orilẹ ède Nàìjíría ati Ivory Coast. Bayii ni Oluwa wi: Awọn olori ẹsìn ni lati gbàdúrà lodi sí ikú àwọn Ààrẹ yii, bi bẹẹ kọ, yoo waye.

"Wọn ni lati gbàdúrà si emi Ọlọrun lati mu ọwọ idajọ lọ silẹ, nitori pe ọkan lára àwọn Ààrẹ yii n ṣaisan. Bo tilẹ jẹ pé inu emi Ọlọrun ko dun, ṣugbọn mo ṣetan lati gba ironupiwada lati ọkan awọn adari wọnyi.

"Bayii ni Ọlọrun wi, bi awọn eeyan ba le gbadura, Ọlọrun yoo sún ọjọ ikú wọn siwaju. Ààrẹ Nàìjíría yoo padanu agbara rẹ nipa àìgbọràn.

"Bayii ni Oluwa wi, mo ti kilọ fun un lai mọye igba, ṣugbọn asiko naa ti to ti ọwọ idajọ Ọlọrun yoo wa sori ẹ nitori àìgbọràn rẹ.

"O kọ eti ikun sí ìkìlọ mi nitori to n bẹrù awọn eniyan. Ààrẹ ati awọn to n. ti i lẹyìn ni yoo gba idajọ, tori pe mo ti fun un ni asiko to, ṣugbọn ko yipada.

"Asiko ti mo fun un lati yipada ti fẹẹ to, nigba ti asiko rẹ ba to, ìjọba rẹ ni wọn yoo le danu, ti wọn yoo si gbe e fun ẹni ti yóò ṣe daradara juu lo."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI