Dapọ Abiọdun bẹrẹ ipolongo idibo ọdún 2023 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Thursday, April 29, 2021

Dapọ Abiọdun bẹrẹ ipolongo idibo ọdún 2023


Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun naa ti fi erongba rẹ han lati du ipo Gomina ipinlẹ Ogun l'ẹẹkeji, iyẹn ninu idibo ọdun 2023 to n bọ.
 
Dapọ Abiọdun sọ pe l'ẹyin t'oun ba pari iṣakoso ẹẹmeji gẹgẹ bi Gomina ipinlẹ naa, o ṣeeṣe k'oun di oluṣọ aguntan, iyẹn bi Ọlọrun ba fẹ.
 
Ana ni Gomina Abiọdun ti sọrọ naa nibi ayẹyẹ ọlọdọọdun ijọba awọn onitẹbọmi, iyẹn Nigeria Baptist Convention, ẹlẹẹkejidinlaadọfa (108th) iru ẹ to waye ni gbọngan Baptist International Conference Centre, to wa ni Lufuwape, opopona Eko silu Ibadan. 
 
Dapọ Abiọdun to l'oun fẹran lati maa ka Bibeli, lati maa kẹkọọ nipa Bibeli ati pinpin awọn ọrọ Bibeli kan sọ pe ko ma ṣe ya ẹnikẹni l'ẹnu wi pe o ṣeeṣe k'oun ba ara oun l'ori pẹpẹ l'ẹyin iṣakoso ọdun mẹjọ gẹgẹ bi gomina.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "O ṣee ṣe ko jẹ ori pẹpẹ ni maa gb'ẹyin si l'ẹyin ti mo ba pari iṣakoso ọdun mẹjọ."
 
Bakan naa lo gba gbogbo ọmọ orilẹ-ede Naijiria l'amọran lati maa tẹle ọrọ ati ilana Ọlọrun ni gbogbo igba, paapaa ninu irin ajo ati ohunkohun ti wọn ba n ṣe.
 
"Gbogbo nnkan ti a nilo ni ibẹru Ọlọrun ninu gbogbo nnkan ti a ba n ṣe. A ni lati maa fi ifẹ lo pẹlu awọn alabagbe ati aladuugbo wa, ka si tun t'ọju ayika wa. Bi a ba n ṣe eyi, a maa gbe igbe aye ayọ, a a si tun ṣe rere laye. 
 
"Eyi to ṣe pataki julọ, a ko gbọdọ gba iwa ipa laaye, ka si maa le alaafia mu ni gbogbo igba. A ni lati maa rin pẹlu ifẹ ati igbọ'ra-ẹni-ye. Nnkan ti Baba wa l'ọrun n reti l'ọwọ wa ree."
 
Bakan naa l'ara awọn to wa nibi ayẹyẹ naa ni Aarẹ tẹlẹri, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ; Gomina Ṣeyi Makinde at'awọn mi in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI