Ileeṣẹ to n ṣe àkóso ina mọnamọna l'orilẹ-ede yìí, Nigerian Electricity Regulatory Commission l'ọjọ Ajé ti i ṣe Mọnde ana ti sọ pé kí gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ máa gbaradi lati san owo ina mọnamọna tuntun to ṣeéṣe kó bẹrẹ nínú oṣù keje ọdún yìí.
Wọn ni àgbéyẹ̀wò owo ina mọnamọna tàwọn ọmọ Nàìjíríà n san yóò wáyé pẹlu awọn ileeṣẹ mọkanla to n pèsè iná f'awọn aráàlú l'orílẹ̀-èdè yìí.
NERC sọ pé àgbéyẹ̀wò náà fẹẹ waye latari bi nnkan ṣe lọ sókè, ìyẹn owo paṣipaarọ agbaye, afẹfẹ gaasi at'awọn nnkan mi in.
No comments:
Post a Comment