Ẹ wo aragbayamuyamu ile ẹkọ ti ijọba Kwara tun ṣẹṣẹ ko n'ijọba ibilẹ Irẹpọdun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 28, 2021

Ẹ wo aragbayamuyamu ile ẹkọ ti ijọba Kwara tun ṣẹṣẹ ko n'ijọba ibilẹ Irẹpọdun


Itan nla gba a n'ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq tun fi balẹ l'awọn agbègbè meji kan to wa n'ijọba ibilẹ Irẹpọdun, ipinlẹ naa.
 
Awon agbegbe naa ti wọn pe ni Agidingbi ati Onila ni Gomina AbdulRazaq ṣẹṣẹ pari kiko yàrá ìkàwé oni yara mẹta sibẹ fún won.

Ile ẹkọ alakọọbẹrẹ ti Nomadic LGEA to wa ni Agindigbi ati ile ẹkọ St. Luke LGEA toun wa ni Onila, nitosi Agbamu ni Gomina AbdulRazaq kọ àwọn yàrá ìkàwé yii sí fún igbadun àwọn akẹkọọ.

Yatọ sí èyí, ijọba Kwara tun pèse omi ẹrọ to ka geere at'awọn nnkan amayedẹrun mi in f'awọn Ara agbègbè meji yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI