Ilẹ Amẹ́ríkà kéde awọn ipinlẹ ti ko ṣe é lọ ní Naijiria, Kwara, Ogun at'awọn ti wọn kò sí níbẹ ree - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 24, 2021

Ilẹ Amẹ́ríkà kéde awọn ipinlẹ ti ko ṣe é lọ ní Naijiria, Kwara, Ogun at'awọn ti wọn kò sí níbẹ ree


Ijọba ilẹ Amẹ́ríkà ti kéde orukọ awọn ipinlẹ ti ko ṣe é wọ nilẹ Nàìjíríà, to sì n gba awọn ọmọ wọn lati ma se lọ s'awọn ipinlẹ naa nítorí àìsí eto aabo to daju níbẹ.

Ipinlẹ mẹrinla ni ijọba ilẹ Amẹ́ríkà sọ pé eto aabo wọn mehẹ, tori awọn iwa ijinigbe, ipaniyan, ati oríṣìíríṣìí aawọ to n ṣẹlẹ níbẹ.

A gbọ pé ipinlẹ mejilelogun, eyi ti ipinlẹ Kwara, Ogun, Eko at'awọn mi ni wa l'ara wọn ni ijọba Amẹrika sọ pé kò sí wahala níbẹ.

Borno, Yobe, Adamawa, Bauchi, Gombe, Kaduna, Kano, Katsina, ati Zamfara wa l'ara àwọn ìpínlẹ̀ tí wọn sọ pé ijinigbe ati awọn agbebọn pọ sí.

Bẹẹ ni wọn tun sọ pé àwọn ipinlẹ bi í Akwa Ibom, Bayelsa, Cross River, Delta, ati Rivers náà ko ṣe é lọ nitori iwa buruku yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI