Awọn ọdọ tun bọ s'aye, ijọba Kwara gbe owo nla kalẹ f'awọn ọdọ lati da iṣẹ silẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 11, 2021

Awọn ọdọ tun bọ s'aye, ijọba Kwara gbe owo nla kalẹ f'awọn ọdọ lati da iṣẹ silẹ



Lati ọjọ Aje-Mọnde ana, iyẹn ọjọ kẹwaa oṣu yii n'ijọba ipinlẹ Kwara ti bẹrẹ eto iforukọsilẹ f'awọn ọdọ lati jẹ anfaani alailẹgbẹ.
 
Gẹgẹ b'AWIKONKO ṣe gbọ, ijọba fẹẹ ya awọn ọdọ ipinlẹ naa ti wọn ni akikanju lati da iṣẹ silẹ l'owo ti ko din ni miliọnu mẹta naira lati fi bẹrẹ okoowo ti wọn ba fẹ.
 
Wọn yoo si da owo naa pada lai ni ele (interest) kankan l'ori. Awọn ọdọ ti ọjọ ori wọn bẹrẹ lati ọdun mejidinlogun si marundinlogoji l'awọn ti wọn yoo l'afaani lati kopa ninu eto ẹyawo yii.
 
Lara ipinnu ijọba lati gbe awọn ọdọ dide, ko si ma ṣe si iyatọ kankan laaarin olowo ati mẹkunnu ni eto yii wa fun.

Ileṣẹ Kwara State Social Investment Programme (KWASSIP) lo ṣ'agbatẹru eto naa gẹgẹ adari ileeṣẹ naa Mohammed Brimah ṣe sọ. 
 
Awọn to ba fẹẹ jẹ anfaani yii la gbọ pe wọn yoo lọ ọ fórukọ silẹ ni http://www.Kwapreneurs.com l'aaarin ọjọ kẹwaa si ọjọ kejidinlogun oṣu yii.
 
Ọdọ ti ko din ni ọọdunrun (300) la gbọ pe wọn yoo kọkọ jẹ anfaani yii, to si jẹ pe l'aaarin ọdun mẹrin, ọdọ ti ko din ni ẹgbẹrun kan ati igba (1,200) ni wọn yoo jẹ anfaani yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI