Awọn olukọ tuntun ni Kwara fẹẹ gba idanilẹkọọ, bẹẹ l'awọn agbẹ tun bọ sinu 'faaji' nla - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, May 8, 2021

Awọn olukọ tuntun ni Kwara fẹẹ gba idanilẹkọọ, bẹẹ l'awọn agbẹ tun bọ sinu 'faaji' nla


Awọn olukọ tuntun ti ko din ni 2,701 t'ijọba ipinlẹ Kwara ṣẹṣẹ gba wọle la gbọ pe wọn fẹẹ gba idanilẹkọọ l'ori ọna ti wọn yoo maa gba lati kọ awọn akẹkọọ l'awọn ile ẹkọ ti wọn ba pin wọn si.
 
Ọjọgbọn  Ṣhehu Raheem Adaramaja to jẹ alaga ileeṣẹ to n ri s'ọrọ eto ẹkọ, iyẹn Universal Basic Education Board (SUBEB) n'ipinlẹ naa lo s'ọrọ yii di mimọ ninu ifọrọwerọ kan to b'awọn akọroyin ṣe. 
 
Nibẹ lo ti sọ pe l'ojuna lati jẹ ki wọn ba eto ẹkọ igbalode mu ni idanilẹkọ naa wa fun, ki wọn si mọ bi wọn yoo ṣe tẹle ilana eto ẹkọ n'ipinlẹ naa.
 
O ni wọn ko ni gba olukọ tuntun kankan s'ẹnu iṣẹ bi wọn ko ba ila idanilẹkọọ naa kọja, tori pe ilana eto ẹkọ igbalode asiko yii ti yatọ si ti tẹlẹ, ti gbogbo wọn si gbọdọ tẹle ilana.
 
Bakan naa ninu iroyin mi in la gbọ pe ileeṣẹ to n ri s'ọrọ awọn agbẹ l'orilẹ-ede Naijiria, iyẹn FADAMA, ẹka t'ipinlẹ Kwara l'awọn ti ṣetan lati fun gbogbo awọn agbẹ patapata l'awọn nnkan amuṣagbara l'ẹka iṣẹ agbẹ ati ọgbin.

Kaakiri ijọba ibilẹ to wa n'ipinlẹ naa la gbọ pe ileeṣẹ Fadama ti fẹẹ fun awọn agbẹ l'awọn nnkan ọgbin ti yoo mu ere pupọ wa fun wọn.
 
Lara awọn nnkan naa ni wọn pe ni: Gari Sieve Machines, Rice Threshers, Maize Sheller, Cassava ( Gari) Grater, Palm Kernel Cracker, Palm Kernel Striper, Rice Milling Machines, Manual Parboiling Machines, Gari Frying Pan, Palm Oil Extractor at'awọn mi in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI