Aye ma n'ika o! Aṣiri Saheed to fẹẹ fi ọrẹ rẹ ṣ'oogun owo l'Ekiti tu o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, May 1, 2021

Aye ma n'ika o! Aṣiri Saheed to fẹẹ fi ọrẹ rẹ ṣ'oogun owo l'Ekiti tu o


"Ẹ ṣ'aanu mi, ẹ da aṣọ aṣiri bo mi" lọrọ ẹbẹ to n tẹnu gendekunrin kan ti ọjọ ori ẹ ko ti ì ju ọdún mẹtalelogun lọ, Saheed Adeniran, ìyẹn akẹkọọ fasiti ipinlẹ Ekiti ti wọn lo o fẹẹ fi ọrẹ rẹ ṣ'owo jade.

Laipẹ yii ni fọ́nrán ibi ti aṣiri Saheed ti tu, ìyẹn lasiko to fẹẹ bẹrẹ sí í pogede lati fi ọrẹ rẹ timọtimọ, ti wọn jọ n gbe inu yara kan náà ṣ'oogun owo.

Awọn kan la gbọ pé wọn n gbọ bi Saheed ṣe n p'ọfọ, to sì n da'rukọ ọrẹ rẹ ti wọn jọ n gbe.

Saheed gbe igba kan to kún fún oògùn abẹnu-gọngọ dani, pẹlu Ado ati aṣọ ti wọn lo o jẹ ti ọrẹ rẹ.

Ibi to ti n p'ọfọ náà la gbọ pé wọn ti Sare wọlé tọ ọ lọ, ti wọn si bá àwọn igba naa lọwọ ẹ.

Ṣe ni wọn dáná iya fún un Saheed, akẹkọọ Ekiti State University (EKSU) naa ko to di pe wọn wọ ọ sita lati fi ṣẹlẹya, to sì n bẹbẹ pé kí wọn foju aanu wo oun.

Awọn ẹlẹyinju aanu la gbọ pé wọn gbà wọn lamọran lati lọ fa Saheed lé àwọn ọlọpaa lọwọ.

Fọ́nrán náà ree:



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI