Ẹ w'oju awọn ogbologbo ajinigbe tọwọ tẹ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 1, 2021

Ẹ w'oju awọn ogbologbo ajinigbe tọwọ tẹ ni Kwara


Ogbologbo ajinigbe márùn un lọwọ àwọn fijilante, ọlọdẹ at'awọn ẹṣọ ọmọ ogun Naijiria ti tẹ n'ipinlẹ Kwara l'Ọjọbọ ti í ṣe Tọsidee ọsẹ to kọjá yii, ti wọn si ti fa wọn le awọn ẹṣọ ọmọ ogun orilẹ-ede yii lọwọ.

Ẹya Yoruba ati Fulani la gbọ pé àwọn tọwọ tẹ yii l'agbegbe Ero Dam to wa ni Odo Owa ijọba ibilẹ Oke-Ero ati ijọba ibilẹ Ekiti, ipinlẹ naa.

Ajọṣepọ awọn Ọlọdẹ, Fijilante ati Ṣọja la gbọ pé wọn fi ri won mu.

Iroyin tó tẹ wá lọwọ jẹ ko ye wa pe ṣe láwọn ajinigbe naa f'ibọn koju awọn oṣiṣẹ eleto aabo náà, ṣugbọn ti ọwọ padà tẹ wọn.

Owo ilẹ yii ati ti Oke Okun la gbọ pé wọn gbà lọwọ wọn lasiko ti aṣiri wọn tú. Awon kan la gbọ pé wọn tà Ileeṣẹ eleto aabo l'olobo nipa b'awọn èèyàn yii ṣe n ji awọn èèyàn gbe.

B'awọn ara agbegbe yìí ṣe rí iṣẹ tàwọn eleto aabo náà ṣe ni wọn ti fi ibinu lọ sile awọn èèyàn náà, ti wọn sì dáná sun mọto, ile ati dukia wọn wí pé àwọn kò fẹẹ ri wọn mọ.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI