Alakoso agba fun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea, Roman Abramovich ti sọ pe oun ti n gbe igbesẹ lati bu ọwọ lu akọni-mọ-n-gba tuntun, iyẹn Thomas Tuchel l'ẹyin ni ipari saa ti wọn n ba lọ yii.
O ni yoo jẹ iwuri fun un f'awọn akitiyan l'aaarin oṣu marun-un akọkọ ni Stamford Bridge.
Tuchel lo gbe ikọ ẹgbẹ agbbọọlu Chelsea de ifẹsẹwọnsẹ to gbẹyin ninu idije Champions League ati FA Cup, to si tun gbe wọn de ipele to l'agbara ninu idije Premier League, ipo kẹrin ni wọn wa lori tabili Premier League.
Wọn l'awọn kudiẹ-kudiẹ kan wa ninu iwe adehun oloṣu mejidinlogun ti Tuchel t'ọwọ pẹlu Chelsea ninu oṣu kinni, eyi ti wọn ni wọn yoo tun agbẹyẹwo rẹ ṣe lati sun un s'iwaju.
Gbogbo igbesẹ la gbọ Chelsea n gbe lati jẹ ki ọdun meji to ba wọn ṣ'adehun tẹlẹ sun s'iwaju si i, ta a si gbọ pe wọn fẹẹ fi kun owo oṣu miliọnu meje Euro (£7million) to n gba tẹlẹ.
AWIKONKO gbọ pe bi Chelsea ba tun le f'ẹyin ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal gbolẹ n'irọlẹ oni, anfaani ti wa fun wọn lati gba ife ẹyẹ Champions League.
No comments:
Post a Comment