Ẹ wo Ẹniọla, ọmọ Kwara to gbe ogo Naijiria yọ ni Spain - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Tuesday, May 18, 2021

Ẹ wo Ẹniọla, ọmọ Kwara to gbe ogo Naijiria yọ ni Spain


Kaakiri agbaye l'awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ti n gbe oṣuba rabandẹ fun Mariam Ẹniọla Bọlaji to gba ife ẹyẹ ẹyin ori papa, ìyẹn Badminton laipẹ yii.

Orilẹ-ede Spain ni Ẹniọla ti gba ife ẹyẹ agbaye naa, nigba to doju akẹgbẹ rẹ lati orílẹ-èdè Ukraine, Oksana Kozyna bolẹ ninu ifigagbaga to waye, eyi to pari si aami ayo meji si ẹyọkan.

Ọsẹ to kọja yii ni idije Para-Badminton agbaye waye, tàwọn eeyan kaakiri agbaye si kopa níbẹ. 
 

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara ti Ẹniọla ti wa, AbdulRahman AbdulRazaq nigba to n gbe osuba kare fun un, o sọ pe orúkọ rere ni Ẹniọla tun ti fun ipinlẹ Kwara si lagbaye bayii, eyi to lo mu ori awon eeyan wu gidi.

AbdulRazaq ni ipenija nla ni bibori naa jẹ, eyi to láwọn yoo bẹrẹ si i tẹramọ gbigbe awọn ọdọ dide lẹka eto ere idaraya, fun ogo Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI