Ko sí ìdàgbàsókè láì sí àwọn oṣiṣẹ - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, May 1, 2021

Ko sí ìdàgbàsókè láì sí àwọn oṣiṣẹ - AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti sọ pé kò sí ìdàgbàsókè kankan tó le ṣẹlẹ nínú ìṣàkóso yala ijọba ibilẹ, ipinlẹ tabi orilẹ-ede láì sí àwọn oṣiṣẹ, pàápàá oṣiṣẹ ijọba, to sì ni pataki ni wọn jẹ fún ìlú.

Oni ti í ṣe ayajọ awọn oṣiṣẹ ni Gómìnà AbdulRazaq sọrọ náà nibi ayẹyẹ tí wọn ṣe lati fi bú ọla fún àwọn káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Bakan naa lo tun ṣèlérí fún gbogbo àwọn oṣiṣẹ wí pé igbe ayé àlàáfíà wọn yóò tubọ máa jẹ òun logun, ati pe gbogbo ẹtọ to ba n tọ sí wọn loun ko ni fi dun wọn.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pé "Ayẹyẹ ọdún yii n waye lasiko ti gbogbo agbaye n koju ijakulẹ ninu eto ọrọ ajé ti àjàkálẹ̀ àrùn Korona, ìyẹn Covid-19 da silẹ.

"Ọrọ ẹgbẹ Labour ye ijọba púpọ, pàápàá lori ọrọ owo oṣù tuntun. Mo fi n da a yin loju pe a ko gboju fo ọ dá, gbogbo ọnà láti mú inú àwọn oṣiṣẹ wa dùn la n wa. Mo fẹẹ ki ẹ f'ọwọsowọpọ pẹlu wa lasiko ti nnkan le koko yìí."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI