Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta
Odu ni Abass Adefulu, ẹni tọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Artunbi Pedepede lagboole sọrọsọrọ nilẹ Yoruba ati lorilẹede Naijiria, ki i si i ṣaimọ foloko, koda, oyun inu gan an ko le sọ pe oun kọ gbọ orukọ Artunbi Pedepede ri.
Lonii ni Abass to kọ iṣẹ lọdọ Yẹmi Ṣonde tawọn eeyan tu n pe ni Jigan Akala, alaṣẹ ati oludailẹ ileeṣẹ redio YSE nilu Ibadan ati lorilẹede yii n ṣe ayẹyẹ ọjọ rẹ.
Gbogbo awọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye ni wọn ti n fi atẹjiṣẹ ikinni ranṣẹ si i lati ki ku oriire fun ti oore ọfẹ nla to tun ri gba lọdun yii.
Ẹmi rẹ yo ṣe ọpọ ọdun laye ninu owo ati alaafia pẹlu ayọ ayeraye laṣẹ Edumare.
Ninu ọrọ toun naa n kọ, eyi to fi n dupẹ lo ti sọ pe:
"Mo ki ara mi ku ayẹyẹ ọjọ ibi oni. Mo gbe orukọ Ọlọrun ga, ẹni to ti n jẹ igi lẹyin ọga fun mi ati opo to di aye mi mu titi donii. Mo gbadura wi pe ọdun yii yoo mu iṣere nla pẹlu igbeleke ati aṣeyọri nla wa fun mi.
"Ẹ ṣeun bi ẹ ti n duro ti mi, ẹyin mọlẹbi, ọrẹ ati ololufẹ mi. Si iyawo mi, Ayọdele Ọmọ Pupa Oloju tête dele ati awọn ọmọ wa, mo nifẹẹ yin titi de Oṣupa."
No comments:
Post a Comment