Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yinbọn pa ọlọpaa n'Ijẹbu Ode - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 20, 2021

Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yinbọn pa ọlọpaa n'Ijẹbu Ode


Ṣe ni ọrọ di boolọ o yago lọna lanaa ti i ṣe Abamẹta, Satide, nigba ti wọn lawọn ọmọ ẹgbẹ kunkun kan koju ija sira wọn, nibi ti wọn ti pa ọlọpaa kan ati eeyan kan danu.
 
 
Agbegbe Igbegba, Garaaji Eko {Lagos garage} atawọn agbegbe mi in la gbọ pe awọn o pa lọlọ nigba ti wahala naa deede ṣẹyọ, tawọn eeyan si sa asala fun ẹmi ara wọn.
 
AWIKONKO gbọ pe ija tani yoo jẹ ọga lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii n ba ara wọn fa lati bi ọsẹ meloo kan sẹyin, ti ko si din lawọn mẹwaa to ti ba iṣẹlẹ naa lọ latigba ti wọn ti bẹrẹ.
 
Bawọn ọlọpaa si ṣe n ko wọn la gbọ pe awọn eeyan naa ko jawọ rara, eyi gan an lo fa a ti wọn fi ṣeku pa ọlọpaa kan lasiko tawọn ọlọpaa tun fẹ lọ koju wọn lati da wọn lọwọ kọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI