Kwara: Ko si nnkan to le da wa duro lati ṣe ipade gbogboogbo wa - APC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 20, 2021

Kwara: Ko si nnkan to le da wa duro lati ṣe ipade gbogboogbo wa - APC


Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, nipinlẹ Kwara ti sọ pe ko si nnkan to le da awọn duro lati ma ṣe ipade gbogbooogbo wọn ti yoo waye laipẹ yii.
 
Oṣu to n bọ la gbọ pe ipade gbogboogbo na fẹẹ bẹrẹ kaakiri awọn ipinlẹ to wa lorileede Naijiria.
 
Ko si nnkan meji to jẹ ki ẹgbẹ APC nipinlẹ Kwara tete sọrọ jade bi ko ṣe ti awọn awuyewuye ati iroyin ẹlẹjẹ ti wọn lo n kaakiri wi pe ko ni i si ipade gbogboogbo nipinlẹ naa at'awọn ipinlẹ meji mi in nitori awọn wahala to jade ninu eto iforukọsilẹ ti wọn ṣe kọja.
 
APC ni iroyin ẹlẹjẹ pọnbele ni iroyin naa wi pe awọn ko ni i ṣe ipade gbogboogbo wọn.

Ninu atẹjade ti alaga fidihẹ ẹgbẹ naa, Alaaji Abdullahi Samari fi sita lo ti sọ pe kawọn eeyan ma ṣe gba awọn ayederu iroyin naa gbọ, nitori ti ko wa lati ojulowo ibi to yẹ ko ti jade.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI