Mbappe ṣetan lati fẹgbẹ agbabọọlu PSG silẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Wednesday, June 23, 2021

Mbappe ṣetan lati fẹgbẹ agbabọọlu PSG silẹ


Gbogbo eto ni wọn lo ti fẹẹ pari bayii, fun gbajugbaja agbabọọlu nni, Kylian Mbappe lati fi ẹgbẹ agbabọọlu Paris Saint-Germain, PSG silẹ lọ sinu ẹgbẹ agbabọọlu mi in.
 
Mbappe to n gba ọwọ iwaju fun PSG la gbọ pe o n gbero lati fẹgbẹ agbabọọlu naa silẹ pẹlu bi wọn ṣe loo ti sọ igbagbọ rẹ nu fun ọjọ iwaju ikọ naa.
 
Ọdun to gbẹyin ree ninu iwe adehun ti Mbappe tọwọ bọ pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu PSG.
 
Wọn lọmọ orileede France naa ti sọ ireti rẹ nu patapata ninu alakooso PSG, iyẹn Leonardo, ti wọn si ni bi saa yii ba pari, yoo ko gbogbo ẹru rẹ to ti di silẹ lọ.
 
Ọmọ ọdun mejilelogun naa ti gba aami ayo mejilelogoji ninu idije mẹtadinlaadọta to ti gba fun PSG.
 
Lille lo gba ife ẹyẹ idije French Ligeu mọ PSG lọwọ, ti Manchester City naa tun ja wọn ninu idije Champions Leage.
 
Lawọn asiko kan, ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid ati Liverpool ni Mbappe n foju sọna fun tẹlẹ, ti a ko si ti i le sọ boya ọkan ninu mejeeji ni yoo gba lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI