Wọn ka ori oku meji mọ gbajumọ babalawo lọwọ, bẹẹ lọwọ tun tẹ awọn mẹta pẹlu ẹjẹ tutu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 30, 2021

Wọn ka ori oku meji mọ gbajumọ babalawo lọwọ, bẹẹ lọwọ tun tẹ awọn mẹta pẹlu ẹjẹ tutu

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta ti tẹ baba agbalagba, ẹni ọgọta ọdun kan ti ko niṣẹ meji ju iṣẹ babalawo lọ, Godfrey Akpudje pẹlu ori oku gbigbẹ meji lọwọ.
 
A gbọ pe awọn agbegbe ọtọọtọ ni Godfrey ti maa n lọ ji saare hu, ti yoo si yọ awọn ẹya ara oku to ba nilo, bi i ori, apa, ẹsẹ ati bẹẹbẹẹlọ.

Obinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ejiro Okoro, lọjọ Ẹti, Tọsidee ọsẹ to kọja yii lo lọ si teṣan ọlọpaa lati lọ fi ẹjọ sun wi pe ẹnikan tawọn ko mọ ri ti ba saare ẹgbọn oun kan tawọn si si Ekpan Ovu, ti wọn si ti ge ori ẹgbọn oun naa.
 
Okoro sọ pe ọdun 2019 lawọn sinku ẹgbọn oun obinrin naa. Eyi lawọn ọlọpaa gbọ, ti wọn fi bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn. Lẹyin o rẹyin laṣiri Godrey tu sita, ti wọn lọ ka a mọle.
 
Bi wọn ṣe dele rẹ ni wọn ti ba ori oku meji ọtọọtọ lọwọ rẹ, to si ti jẹwọ pe loootọ ni, ati pe ipinlẹ Ọṣun lọdọ babalawo kan to ti ku loun ti ra ori oku ka yooku.
 
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Bright Ẹdafe fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, oun lo si jẹ ko ye wa pe Godfrey ti wa lahamọ awọn, ati pe o ti n jẹwọ awọn iṣẹ ibi to ti ṣe sẹyin, atawọn eyi to n gbero lati ṣe.
 
Bakan naa ninu iroyin mi in to jọ ara wọn la gbọ pe ọwọ ọlọpaa tun ti tẹ awọn mẹta kan lọjọ Aje, Mọnde, ijẹta yii ni ikorita Nsukwa to wa lopopona Ogwashi-Uku si Kwale.
 
Nnkan bi aago mọkanla aabọ la gbọ pe awọn ọlọpaa ti wọn pe ni Dragon da wọn duro ninu mọto bọọsi Sienna, lasiko ti wọn n rin irin ajo lati ilu Asaba lọ si Kwale.
 
Funra awọn eeyan yii ni wọn gba fawọn ọlọpaa lat yẹ wọn wo finnifinni, to si jẹ iyalẹnu nigba ti wọn ba igba nla kan to kun fun ẹjẹ tutu, to jẹ ẹjẹ eeyan ẹlẹran ara.
 
Native doctor arrested with human skulls in Delta( photo) 
Awọn mẹta naa ni Monday Nwite, ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn; Madabuchi Nweke, ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn ati Nwite Sunday toun jẹ ọmọ ọdun mọkanlelogun. Abule kan ti wọn pe ni Ebenta, ni ijọba ibilẹ Ohaukwu, ipinlẹ Ebonyi lawọn mẹtẹẹta ti wa.
 
Loju ẹsẹ lawọn mẹtẹẹta ti jẹwọ wi pe awọn ṣẹṣẹ pa ẹnikan tan ni, tawọn si gba ẹjẹ rẹ sinu gba. Wọn ni ọdọ babalawo lawọn n gbe ẹjẹ naa lọ lati fi ṣẹṣo fun wọn.
 
Yatọ si igba ẹjẹ ti wọn gba lọwọ wọn, wọn tun gba ṣeeni ti wọn fi oogun abẹnugọngọ yi lara lọwọ wọn.
 
Ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Muhammed Ali ti sọ pe awọn eeyan naa k ni lọ lai jiya ẹṣẹ wọn labẹ ofin orileede yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI