Wọn pa Hassana danu, wọn tun ge nnkan ọmọbinrin ati ọmu rẹ mejeeji lọ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Saturday, June 12, 2021

Wọn pa Hassana danu, wọn tun ge nnkan ọmọbinrin ati ọmu rẹ mejeeji lọ ni Kwara


Lasiko ti a pari iroyin yii, ko ti i sẹni to le sọ pe bayii ni wọn ṣe pa obinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Hassana Mohammed lọjọ kẹwaa, ọsu yii, iyẹn Ọjọbọ, Tọside, to kọja yii lagbegbe Kanikoko to wa niluu Kaiama, ipinlẹ Kwara.


Bo ti;ẹ jẹ pe ki i ṣe bi wọn ṣe pa Hassana lo n jẹ kayeefi fawọn to ri oku ẹ nilẹ, bi ko ṣe bi wọn tun ṣe ge nnkan ọmọbinrin rẹ ati ọmu rẹ mejeeji salọ.
 
Nnkan bi aago mejila aabọ ọsan ọjọ naa la gbọ pe awọn eeyan ṣawari oku Hassana lẹgbẹ opopona, ti wọn si sare ranṣẹ sawọn eleto aabo Sifu Difẹnsi lati fi to wọn leti

Babawale Afọlabi, to jẹ alukoro ileeṣẹ eleto aabo naa lakooko to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ lo jẹ ka mọ pe agboole  Yarugaba to wa ni Kaiama ni Hassana n gbe.
 
O ni bawọn ṣe ri oku rẹ naa, ko yatọ si pe wọn pa a danu lati fi ṣẹṣo ni. 
 
Bo tilẹ jẹ pe o ni wọn ti pada sin oku naa lanaa, ṣugbọn awọn ti bẹrẹ iwadii lati mọ iru iku to pa a.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI