Wọn sọ Mikel Obi di Ambasidọ awọn ọdọ ni Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 20, 2021

Wọn sọ Mikel Obi di Ambasidọ awọn ọdọ ni Naijiria


Ijọba apapọ orileede Naijiria ti sọ balogun fun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles, John Mikel Obi di aṣoju awọn ọdọ lorileede yii, lati le jẹ kawọn ọdọ to ṣẹṣẹ n dide bọ le maa ri i gẹgẹ bi awokọṣe lati de ibi giga.
 
Papa iṣere apapọ orileede yii to wa ni Surulere l'Ekoo ni minisita fọrọ eto ere idaraya lorileede yii, Sunday Dare ti sọ ọ di mimọ pe awọn fẹran ọna ti Mikel gba ṣe awọn aṣeyọri ẹ.

O ṣapejuwe Mikel, agbabọọlu Chelsea naa tẹlẹ gẹgẹ bi ẹni ti awokọṣe rẹ ko le parẹ lailai, nitori to ti ṣi oju awọn eeyan si ere bọọlu alafẹsẹgba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI