Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka ti gba ijọba orileede yii lamọran wi pe ki wọn tete tọrọ aforojin lọwọ Oloye Sunday Adeyẹmọ, tọpọ awọn eeyan mọ si Igboho ni kiakia, dipo ki wọn maa le e kaakiri bi ọdaran.
Laipẹ yii ni Ọjọ Ṣoyinka sọrọ naa lasiko to n bakọroyin BBC sọrọ nipa nnkan to ri si bawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ṣe lọ sile ẹ, ti wọn si ba ibẹ jẹ, pẹlu pe wọn tun pa eeyan meji ti wọn jẹ alabaṣiṣẹpọ Igboho.
Ọjọgbọn Ṣoyinka sọ pe bi ijọba apapọ ṣe lọ sile sile Igboho lai gba aṣẹ, ti wọn si tun ba awọn dukia rẹ jẹ ko bojumu to, ati pe o ku diẹ kaato.
Ninu ọrọ baba naa, "Amọran mi sijọba apapọ ni pe ki wọn yee le Igboho kaakiri ọdaran, nitori pe ẹ ti bẹrẹ lati maa le kaakiri nipa ẹsun ọdaran ti ẹ fi kan an.
"Bi Igboho ba tiẹ wa a koju ofin, o da mi loju wi pe ijọba orileede yii ni oju maa ti. Mo ro pe ohun to yẹ ki wọn sọ fun Igboho ni pe 'A ti ṣe aṣiṣe, ko yẹ ka ṣe nnkan ti a ṣe yii, a ko wa ẹ mọ, pada si ile rẹ.' Ko da, ki wọn sin in dele lati bẹrẹ igbe aye rẹ pada.
Siwaju si i ni Ṣoyinka tun sọ pe bi Igboho ṣe n ja fun ominira ko ṣẹyin bawọn ọdaran kan ṣe n da alaafia orileede yii laamu, ti wọn si tun ni atilẹyin awọn baba-n-gbẹjọ.
Bakan naa lo sọ pe bo tilẹ jẹ pe oun ko faramọ orileede Oduduwa ti wọn n pariwo, sibẹ o ni atunto ni orileede yii nilo, ki gbogbo nnkan si maa lọ bo ṣe yẹ.
No comments:
Post a Comment